Seneto Yayi Pada Siluu Eko, Ifokanbale Fun Gomina Amosun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, July 3, 2018

Seneto Yayi Pada Siluu Eko, Ifokanbale Fun Gomina Amosun

Opo awon eeyan ti won gba ti Seneto Solomon Olamilekan Adeola tawon eeyan mo si Yayi, iyen Seneto to n soju ekun Lagos West nile igbimo asofin agba niluu Abuja, eni to tun fe e jade dupo gomina ipinle Ogun lodun 2019 ni inu won ko fi taratara dun pelu bi okunrin naa se so pe oun fe e pada siluu Eko lati loo tesiwaju oselu oun niluu Eko.


Ale ana, iyen ni nnkan bi aago mesan ku ogun iseju ni okan lara awon alatileyin Seneto Yayi fun idibo gomina odun 2019 nipinle Ogun, Ogbeni Ogunpola Damilola Damochee gbe iroyin naa jade sori ero ayelujara abanidore, iyen Facebook, to si je kawon eeyan mo pe Yayi ko se gomina ipinle Ogun mo, o ti pada siluu Eko bayii.

Bawon kan se n so pe Seneto Yayi kan fe e wa farahan nipinle Ogun ni, kii se pe o mon-on mon fee dupo naa, ati pe lati gbe emi gomina Ibikunle Amosun soke lasan ni, bee lawon kan n so pe ona ti ko gba a lo je ko pada sibi to ti n bo.

Fawon to ba mo nnkan to n lo daadaa latari idibo gomina to n bo lodun 2019 nipinle Ogun, won a mo pe kii se pe Gomina Ibikunle Amosun ko gba ti Seneto Yayi, sugbon ona ti okunrin kukuru naa gba wole lo mu ki Amosun tako o, ti ko si faaye gba ninu egbe oselu APC tipinle Ogun.


Bo tile je pe awon omo eyin Seneto Yayi nipinle Ogun ti bere sii kuro leyin e lati bii ojo meloo kan seyin, ti won si lo n satileyin fun Omoba Gboyega Nasiru Isiaka toun naa fe e jade dupo kan naa yii, paapaa nigba to tun loo darapo mo egbe oselu ADC, nitori ti won ko fe e padanu ona meji.

Ohun tawon kan n so ni pe, lati le je pe ki erongba awon Yewa lati di gomina ipinle Ogun le tete wa si imuse lo mu ki Seneto Yayi pinu lati gbe ipo naa sile fun GNI, ko ma ba a je pe won tun padanu lodun 2019.

Gege bi awon kan ta a foruko bo lasiri se so lai pe yi, won ni ipinu Seneto Yayi ti ogunlogo awon eeyan nipinle Ogun feran e daadaa, nitori pe o lawo, o si je eeyan gidi niluu Eko to ti n bo lo mu ki iporuru okan de ba Gomina Amosun, ti ko si je jo mo eni to fe e fa kale lati ba Seneto naa jijakadi lakoko idibo.

Ni bayii, irorun ati ifokanbale ti de bayii fun gomina ipinle Ogun, Asofin Agba Ibikunle Amosun lati sun oorun asundokan lori ipinu e lati fa adije sipo naa kale.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI