IJOBA APAPO ATIJOBA IPINLE OGUN TOWO BO IWE ADEHUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, July 31, 2018

IJOBA APAPO ATIJOBA IPINLE OGUN TOWO BO IWE ADEHUN

Bi e se n kan iroyin yi lowo, inu idunnu ati ayo lawon omo ipinle Ogun wa bayii latari bijoba apapo atijoba ipinle Ogun se towo bo iwe adehun lati so isoro ai ri omi lo di ohun igbagbe.


Gege ba a se gbo, oniii, ojo kokanlelogbon osu keje ni ipade naa waye lagbegbe Ota, ipinle Ogun, nigba ti Gomina Ibikunle Amosun gba awon osise ijoba apapo lalejo lati wa iyanju si isoro ai ri omi fawon araalu n koju.


Be e ba gbagbe, o ti le ni ogbon odun (30years) ti won ti bere sise omi ero igbalode siluu Ota, sugbon ti won ko pari e latigba naanaa, sugbon ni bayii, ona ara ni eto naa gba yo.


Ijoba ipinle Ogun ti wa a seleri lati se atunse lori awon opa omi naa lai pe leyin iwe adehun ti won towo bo naa, to si mu kawon araalu Ado-Ota maa korin iwuri ki Gomina Amosun.


Won ni asiko to dara gan an ni won pinu lati se iranlowo fawon ara agbegbe naa, ki won si maa ri omi lo lasiko to ba ye.No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI