NITORI IDAJO IKU: AWON ELEWON FE E LU ADAJO PA NI KOOTU - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, August 1, 2018

NITORI IDAJO IKU: AWON ELEWON FE E LU ADAJO PA NI KOOTU

Se loro di boo lo o yago lona lojo Tusde to koja yi nigba fawon elewon kan ti won da ejo iku fun so pe a fi kawon lu adajo to da ejo iku fun won pa, ki gbogbo won si jo pade lorun alakeji.


Ile ejo to wa lagbegbe Ikot Ekpene niluu Uyo, ipinle Akwa Ibom loro naa ti sele nigba ti won so pe awon elewon naa ti won ko wa lati ipinle Rivers loo koju ija si adajo Okon Okon pe idajo iku to se lowo ninu, ti ko si ye ko ri bee.

AWIKONKO gbo pe lesekese ti adajo naa ti pase pe ki won loo yegi fawon adigunjale naa ni won ti bere sii soko oro sii, ti won n buu, to fi di pe won fe e lo luu pa ko too di pe awon olopaa to wa layika da won lowo ko.

Bee ni won tun seleri pe gbogbo awon yoo pa gbogbo igbimo tijoba ipinle naa gbe kale lati maa ri si oro idajo, ti onikalu si bere sii sa kijo-kijo lati du emi ara won.

Fun bii wakati kan gbako la gbo pe awon odaran naa fi da wahala sile, to je pe awon olopaa atawon eso ologun ni won sese ka won lowo ko, ti won si ko won sinu moto ti won fi n gbe awon elewon.

Awon elewon naa ni Bernard Efe Ajomaya, Christian Charles Naya, Daniel West ati Shedrach Dick Dala. A gbo pe ojo kokandinlogun osu karun odun 2015 ni won jo Dokita kan, Usen Bassey gbe ninu osibitu e, Ini Abasi Clinic to wa niluu Uyo.

Egberun mewaa naira la gbo pe awon ajinigbe naa n beere ki won to o le fi Dokita naa sile, sugbon ti asiri won pada tu sawon olopaa lowo, ko too di pe won foju won bale ejo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI