IPINU RERE NI MO NI FUN IPO GOMINA IPINLE OGUN - SEGUN ODEGBAMI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, July 18, 2018

IPINU RERE NI MO NI FUN IPO GOMINA IPINLE OGUN - SEGUN ODEGBAMI

Okan lara awon ilu mon on ka agbaboolu agbaye fun orileede Naijiria tele ri, Oloye Segun Odegbami ti rawo ebe sawon omo ipinle Ogun pe ki won ran oun lowo lati de ipo gomina lodun 2019 latari ipinu rere toun ni fun ipinle naa.Segun Odegbami to je omo bibi ilu Imo, Abeokuta lo soro naa losan onii niluu Abeokuta lasiko to n so erongba e lati jade dupo gomina lodun 2019 labe egbe oselu Labour (Labour Party).

Nibe lo ti je ko di mi mo pe bo tile je pe oun kii se oloselu to be e ge, sugbon ipinu rere ati afojusun gidi toun ni fun ipinle oun tii se Ogun lo je koun fe e lo iriri irin ajo kaakiri agbaye lati fi mu idagbasoke alailegbe ba ipinle naa.

O tenu mon on pe kii se ipo to ye ki ipinle Ogun wa lo wa lonii, idi si ni yii toun fi wo o pe ona wo loun le gba lati ran ipinle naa lowo, bi ko se koun jade dupo eni akoko nipinle naa.


Bakan naa nigba to n so idi pataki to fi yan egbe oselu Labour laayo, o so pe egbe naa loun rii pe won ni ojo iwaju rere fun orileede Naijiria, ti ko si soro eleyameya nibe. O wa rawo ebe sawon araalu pe ki won gbaruku ti oun basiko idibo ba ti de.

Bee lo tun ro awon araalu pe ki won tete loo gba kaadi idibo alalope, PVC won ko too pe ju, lati le loo gege bi agbara ti won ni lati gbe eni to wun won lokan wole.

Nigba toun naa n soro, alaga egbe oselu Labour nipinle Ogun, Komureedi Abayomi Arabambi so pe kii se pe awon deede tewo gba Segun Odegbami gege bi adije sipo gomina ipinle Ogun si egbe won, bi ko se pe awon itan rere to ti ko fun orileede Naijiria.

O sapejuwe Odegbami gege bi eni tawon omo orileede yi ko le gbagbe latari bo ti se gbe oruko Naijiria ga kaakiri agbaye lasiko to n gba boolu, ati pe iriri irin ajo e kaakiri awon orileede lo fe e fi mu idagbasoke ba ipinle Ogun.

Bakan naa nigba to n bu enu ate lu ijoba Ibikunle Amosun to je gomina ipinle naa, Arabambi so pe isejoba etanje ni Gomina Amosun n lo lati fi bawon eeyan se, ati pe ijoba to n se ko ye e rara.


O ni kaka ki Gomina Amosun gbajumo wahala to n sele niluu e, se loo gba ipinle Ekiti ti ko kan an lo lati loo mojuto eto idibo nibe, eyi ti ko bojumu to.

Bee lo rawo ebe sawon omo egbe oselu naa pe ki won maa loo fa awon eeyan wa sinu egbe, ki won le sagbateru egbe naa de ipo giga, ati pe ki won le joo je igbadun eto oselu awaarawa.

Lara awon to wa nibi eto naa ni gbajumo akotan, Ogbeni Tunde Kelani to je alaase ileese Mainframe, Onarebu Sina Aroyehun atawon min in.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI