ONI JIBITI LAWON EEYAN MAA N FERAN - VAN GARUBA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, July 18, 2018

ONI JIBITI LAWON EEYAN MAA N FERAN - VAN GARUBA

Gbajumo sorosoro ori redio to sese n dide bo nipinle Ogun, Ogbeni Ibrahim Abubakar Kehinde Garuba topo awon ololufe e mo si Van Garuba ti so pe oni jibiti, gbajue nikan lawon eeyan maa n feran, won kii feran eni to ba n so ododo oro fun won.


Van Garuba tawon araalu n gba ti e lasiko yi lo je ko di mi mo losan onii, Wesde lasiko to n dahun orisirisi ibeere lenu AWIKONKO, paapaa lori bi ko se ri tii ri ipolowo gba fun eto e to n se.

Okunrin omo bibi ilu Oyo naa so pe ko rorun lati maa so otito oro lori redio nitori pe awon araalu ti won n ba so otito ko se tan lati gbo otito oro, o ni awon oro bi efe ati awada ni won maa n feran, eyi ti ko bojumu to.

Garuba ninu oro e, o so pe "Oro eto sise lori redio ko rorun fun eni to mu ododo ni okunkundun lati maa so, nitori pe awon eeyan feran eni to ba n so nipa oro efe tabi eni to n fi awon eeyan dapara.

"Iru awon eeyan be e ni won maa n feran lati se onigbowo fun, sugbon k'eeyan maa soro lori redio, ki eeyan maa bawon oloselu so ogidi oro lati to won s'ona, irufe eni to n so nipa oro orileede Naijiria pelu erin ati efe bii ti Gbenga Adeboye."

O tun je ko di mi mo pe opo awon ololufe awon sorosoro lo je pe eto ori redio nikan ni won feran lati maa gbo, won ko se tan lati dide iranlowo, yala nipa sise onigbowo tabi gbigbe ipolowo oja fun won.

Garuba tenu mon on pe nipa gbigba ipolowo oja lowo awon araalu ni won fi n ri owo eto san lati maa fi dawon eeyan larayalaraya, sugbon tawon eeyan ko ri be e.

Nigba to n soro lori awon eto to ti se, Garuba so pe opo awon eeyan ni won n pe oun pe koun gbe rekoodu awon toun ti se jade fawon eeyan lati rii ra, sugbon to je pe awon toun yoo fi gbe jade ko si nile.

Lara awon eto e to lawon araalu n beere fun ni Ile Alaja Meta, Sibi Onide, Omo Iya Tin S'akoso Aye, Ileri Akuse atawon min in.

Nigba to n rawo ebe sawon araalu lati dide iranlowo fun, o ni kii se pe won n gbadun won lori redio nikan lo n je pe won n fi ife han si won, nitori pe bawon se n soro.lori redio naa, owo ni won n lo.

O ni lara awon nnkan ti won le fi fife han si won ni pe ki won gbe ipolowo wa fun won lati le je ki eto e to pe ni "O N SELE" nileese redio Family 88.5FM, Abeokuta le maa tesiwaju.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI