KO SI AWUYEWUYE NINU EGBE PMAN MO - SAMMY B - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, July 10, 2018

KO SI AWUYEWUYE NINU EGBE PMAN MO - SAMMY B

Gbajumo olorin nni, Komureedi Samuel Balogun topo awon eeyan mo si Sammy B ti je ko di mi mo pe ko si awuyewuye to n lo kankan mo ninu egbe awon olorin to darapo, iye Performing Musician Employer Association of Nigeria, PMAN, paapaa nipinle Ogun.


Sammy B to tun je akowe egbe naa lo tan imole soro yi lonii ojo Isegun leyin ipade egbe tawon oloye tuntun egbe naa se pelu Alaaji Sefiu Alao, Baba Oko nipa ti ile egbe won tuntun ti won sese gba sadugbo Lafenwa.

O so pe ko si ki awuyewuye tabi wahala die ma fe waye ninu egbe paapaa to ba ti di oro oselu, sugbon gbogbo lawon ti yanju nitori pe awon to padanu nibi idibo naa ni won ti pada wa, tawon si ti jo n se papa.

Sammy B so pe nibi ti ife to wa laariwon ba yii de, alaga ana naa fowosowopo pelu won nipa awon nnkan ti won n se lati rii pe idagbasoke ati isokan wonu egbe naa, nitori naa kawon omo egbe to ku ti won si n binu naa fi owo wonu, bi oro oselu se ri niyen.

Gbajumo olorin naa so pe PMAN kii se egbe (association), isokan (union) ni, nitori e ni ko se le rorun fenikeni lati so pe boya awon tun fe e da egbe min in sile loruko PMAN.

Nigba to n soro lori ile egbe won ti won yoo ti maa sepade, paapaa awon nnkan ti won fe e koko se gege bi oloye tuntun, Sammy B lawon ti kuro nile isembaye tawon nko gege bi ofiisi tele, iyen ile Oloogbe Yusuf Olatunji ti PMAN ti jade, eyi to wa ni Abule Otun.

O lawon ti gba ofiisi min in to joju ju eyi tawon n lo tele lo, Lafenwa lo si wa.

Bakan naa lo so pe awon ileese min in yato si ileese Goldberg ni won ti towo bowe adehun pelu won lati jo maa sise papo.

PÍN-IN KÁÀKIRI