OKO MI FE KI N BIMO OKUNRIN LEYIN ODUN MEJILELOGUN, E GBA MI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, July 7, 2018

OKO MI FE KI N BIMO OKUNRIN LEYIN ODUN MEJILELOGUN, E GBA MI

E ku deede asiko o, Iroyin Awikonko, mo mu ikinni wa fun yin. Mo fe e je ki e mo pe okan lara awon ololufe yin ni mo je, ko si sigba ti mo ka iroyin yin, ti inu mi kii dun, nitori pe mo nife lati maa ka iroyin l'ede Yoruba to je ede abinibi mi. Mo ni lati gbe oriyin fun un yi pelu ise ti e n se nitori pe ko rorun lati maa ko iroyin ni ede Yoruba. Odun to koja ni mo salabapade iroyin Awikonko, mi o kan ranti boya osu kesan an tabi osu kokanla ni mo koko pade iroyin yin ni, sugbon mo mo pe inu osu baa-baa-baa ni, iyen (ember months).

Mi o ni fe e soro ju, sugbon latigba ti mo ti maa n ka iroyin yin, abala kan ti mi o ri ki e fi kun un ni ti abala awon to ba nilo iranlowo nipa pe ki awon araalu gba won nimoran. Bii iru emi bayii, mo nilo amonran awon eeyan, sugbon isoro kan soso ti mo ni ni pe mo maa n tiju, nitori e ni mi o se ni fe ki e fi nomba mi tabi foto mi han sita fawon eeyan.

Ki n too bere oro mi, e je ki n fi die nipa mi han yin, oruko mi ni Arabinrin Olanike Akeusola, omo bibi ilu Akoka nipinle Ondo ni mi, mo si ti le die ni aadota odun (50+), mo ti ni omo meji, obinrin si lawon mejeeji. Osise ijoba ni mi, ilu Ibadan labe ijoba ijoba ipinle Oyo ni mo si ti n sise, nitori pe omo bibi ilu Ogbomoso ni oko ti mo fe.

Odun 1989 ni mo koko pade oko ti mo fe, nigba ti a wa ni Yunifasiti tiluu Akure, iyen FUTA. Lojo ti a maa koko pade, enu ona ofiisi egbe awon akekoo la ti pade, mo loo san owo tawon akekoo maa n san lodoodun, iyen dues nigba yen ni, bi mo se fe e jade sita lo ri mi, emi o ti e kuku gbe oju soke, nitori pe mo n gbiyanju lati fi iwe pelebe owo mi sinu faili ti mo gbe dani ni, oun lo ri mi, to si sare wa a ba mi.

Abiodun loruko e, ipele keta leka imo sayensi lo wa, emi si sese wole sibe ni, mi o tii mo ibikankan rara ninu ogba naa, ko da a, mi o tii mo enikankan rara.  Bo se wa a ba mi, lo so pe oju mi jo otuntun ninu ogba yi, mo si daa lohun pe beeni, sa, ki n ma fa oro gun, ibi ti a ti bere ore wa niyii, ti ko si seni ti ko mo awa mejeeji gege bi ololufe ninu ogba FUTA lodun naa lohun.

Bi awon ore Abiodun ba ri mi pelu okunrin min in, lesekese ni won a ti se gboborun Abiodun, toun naa yoo si maa gbe ija bo wa a ba mi, o digba ti n ba salaye iru eni ti okunrin naa je fun un pelu aridaju ki ara e too bale, bee naa lo ri to je pe bi awon ore mi, tabi ore Abiodun ba rii to n ba obinrin min in sere to fe e le ju, lesekese lawon naa yoo ti so fun mi, sugbon emi kii gbe ija lo ba o nitori pe oju maa n ti mi, paapaa ki n maa ja lori okunrin, bo tile je pe mi o le fi sere rara fun iseju kan.

Lati ge oro mi kuru, bayii la se titi ti Abiodun fi jade, to si fi lo sin orileede baba e ni Kano, se e kuku mo pe ko si foonu nigba naa, sugbon a maa n fi leta ranse si ara wa, titi temi naa fi setan. Odun 1996 la pada se igbeyawo alarinrin. Ko da a ojo manigbagbe lojo naa je fun emi ati oko mi, nitori pe ojo naa ni won fiwe ranse si oko mi pe ko wa a di igbakeji alaga ileese kan ti mi o ni fe e daruko sita.

Ti n ba ni ki n maa soro, leyokookan, maa gba asiko yin, idi ni yii ti ma a se ge oro mi kuru, ki ejo mi ma baa poju fawon to fe e gba mi lamonran. Loro kan sa, igbeyawo emi ati Abiodun so eso meji, obinrin lawon omo mejeeji ti a bi, akobi wa je omodun mejilelogun ni, o si ti wa ni ipele keji ni Poli kan ti mi o ni daruko. Bee, omo wa keji toun je omodun metadinlogun sese pari ileeko girama lodun yi ni, ko si nii pe e wo fasiti.

Omo meji ti Olorun yonda fun emi ati oko mi re e, kii se pe mi o kii loyun, sugbon se ni oyun naa ma n ba je mo mi lara, eyi to tun pada duro ti mo fi bimo okunrin lodun 2015, omo naa ko pe osu meta to fi ku. Ko si too di asiko yen, awon ebi oko mi ti n parowa fun oko mi pe ko loo fe iyawo min in to maa bimo okunrin fun un, nitori pe okunrin ni yoo je arole, ti ko si nii je ki oruko baba won pare. Lojo kan ni egbon oko mi to n gbe ni Abuja pe mi lori aago, to si n beere lowo mi pe igba wo ni mo maa yan oko mi kuro ninu agan, oro yi ko koko ye mi, sugbon nigba to ya ni won je ki n mo pe obinrin ti ko ba bimo okunrin fun oko e, ko yato si agan nitori pe bawon omo ba je obinrin, oko awon omobinrin naa lo maa je gbogbo ogun won.

Ti m ba ni ki n maa so gbogbo awon nnkan ti oju mi ti ri nile oko mi, oro yi yoo gun ju, o si see se ko su awon to fe e gba mi nimonran. Bo tile je pe oko mi naa ma n parowa fun mi, to si mo ipo tawon dokita so fun un pe mo wa, paapaa nigba ti mo bimo abigbeyin ti ko si laye mo, to tun wa a je okunrin. Ohun ti dokita so ni pe kii se pe mi o le bimo mo, sugbon ki n ma gbiyanju e nitori pe o le mu emi mi lo, ati pe yato si ti ojo ori mi, wahala ti mo ti se lawon igba ti mo n loyun to n baje naa ko le faaye gba mi mo lati so pe mo tun fe e loyun min in.
Gbogbo bawon ebi oko mi n so fun oko mi pe ko loo fe iyawo min in sita ti yoo bimo okunrin fun lo maa n so fun mi. Abiodun nife mi pupo, o si mo pe emi naa kii se eni to feran wahala. Nipase mi ni Abiodun oko mi fi ri ise to n se, ta a si ti ko ile meta, meji la fi renti fawon ayalegbe, eyokan to ku la n gbe.

Owo wa lowo oko mi daadaa, o si maa n se iranlowo fawon eeyan, bee lo tun maa n ya awon eeyan lowo. Ko seni to wa iranlowo de odo Abiodun teminikan ti kii saanu fun won. Ibi ti mo ti wa a ni isoro bayii ni pe, lose to meta seyin ni oko mi pe mi, to bere sii so orisirisi oro pe se mo mo pe itiju lo n je foun nigboro pe a o bimo okunrin, to simlawon ore oun maa n pa asamo moun lasiko tawon ba n se faaji, tabi soro lowo. Abiodun so pe toun ba ti e fe iyawo le mi, ife toun yoo ni si iru iyawo bee ko le to idaji eyi toun ni si mi.

O je ki n mo pe oun nife mi gidigidi, ti ko si si eni to le yo ife mi kuro lokan oun, ko da to seleri fun mi pe ko si nnkan ti mo n beere lowo oun, toun ko nii se fun mi. Nnkan kan ti mo mo ni pe latigba ti oko mi ti ri ise to n se, lo ti so pe ki n pa ise ijoba ti segbe kan, ki n di iyawo inu ile, nitori pe oun fe ki n maa daamu, tabi se wahala, sugbon emi ni mi o gba fun un.

Nibi ti a ni oro de, bi awa mejeeji ba so pe a o se ise onise mo, nnkan ti a maa je di ojo ale pelu awon omo wa ti wa nile, sugbon se eyin naa mo pe nnkan to n lo lorileede Naijiria lonii, ko faaye gba pe keeyan kan jokoo lasan lai se nkankan. Awon araadugbo gan an a fura si iru eni bee pe o see se ko je pe oogun owo ni won se, nitori pe eni tawon eeyan n ri to kan n mura, ti won si rii pe eni bee ko nise lowo, iye meji lo maa flje fawon eeyan to ba n ri won.

Abiodun mi so fun mi pe ibi ti awon omo mi ba fe e ka iwe de loun setan lati ran won lo, bo tile je pe awon omo wa yi akanti kan ta a si fun won si okan lara awon ile ifowopamo to gbajumo daadaa, ti won ko si tii mo nipa e, osoosu la n fi owo sibe fun won nitori ojo iwaju won. Ko si nnkan ti won n fe ti a o kii fun won, to si je pe o ba won je pe ki won maa yo ayoporo. Awon omo rere ni Olorun fi jinki wa, ti won si nitelorun, bee ni won tun ni iteriba, bakan naa ni won n se daadaa lenu eko won.

Ose meta seyin ti oko mi ti ba mi soro yi ni okan mi ko ti bale mo, to si ti fe e so mi di nnkan min in, se eyin naa mo pe orisa je n pe meji obinrin ko denu, kii se pe boya mo mi o fe ki oko mi fe iyawo le mi, sugbon iru eeyan wo gan an ni oko mi fe e fe, orisirisi obinrin lo si wa nita bayii, to je pe eranko lo po ju, ti won a si maa se bi eeyan gidi, o digba ti won ba wole tan.

Mi o kan fe ki oko mi loo gbe obinrin to maa so idile wa di ahoro nipa lilo imo taraeni-nikan ba wa lo po. Se eyin naa mo pe bi oyun ba ti de bayii, gbogbo aye lo maa di igba ikole lowo awon obinrin to wa nita bayii, paapaa awon obinrin to je pe owo ati bi won yoo se gba dukia ti won ko sise fun ni won ma maa wa. Gbogbo awon ero okan mi yi ni ko je ki n ja fafa bii ti tele, oko mi gan an n sakiyesi pe nnkan n se mi, sugbon ko beere lowo mi, o see se ko ti mo pe ironu oro to ba mi so lo ni mo n ro. Fun bi ojo meta ni mi o fi lo sib'ise to je pe mo sa a kan wa nile ni.

Ounje gan an ko lo lenu mi daadaa bii ti tele, lojo Tusde to koja yi ni mo lo si osibitu ta maa n lo, iyen eyi ti won n pe ni family osibitu lati loo se ayewo, a fi bi eni pe awon dokita maa n riran bi awon wolii ni, aya mi ja nigba ti won beere lowo mi pe kinni mo n ro lokan, won beere pe ki lo n gbe mi ninu nitori pe iru e ko sele ri latigba ti mo ti n lo sayewo nibe. Oro ko se e so, mo kan so fun won pe ko si nkankan ni, ati pe mi o mo nnkan to n se mi lo je ki n wa, ko da a, lojo naa, dokita fe e pe oko mi lati beere lowo e pe kinni mo n ro, ebe ni mo sare be pe ko ma dan an wo.

Mo nigbagbo ninu Iroyin Awikonko pe e maa ran mi lowo lati ri ona abayo si isoro ti mo ni yii lo je ki n farabale te atejise yii lati fi ranse sii yin, ki awon eeyan le gba mi nimonran. Gege bi mo se so fun un yin pe mi o fe ki e fi adiresi mi sita. E seun, maa maa reti esi yin.

Fun eyin ololufe wa, yato si pe e fi oro amonran yin ranse nibi, e tun le fi ranse email wa; [email protected] tabi lori WhatsApp wa; 07012342712.


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI