KO SI EGBE OSELU TO DA BI EGBE OSELU ACCORD NIPINLE OGUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, July 25, 2018

KO SI EGBE OSELU TO DA BI EGBE OSELU ACCORD NIPINLE OGUN

Adije sipo omo ile igbimo asoju-sofin kekere (House of Reps) niluu Abuja lodun 2019, Dokita Ibrahim Adesina Olaleye ti so pe ko si egbe oselu to gba alaafia laaye nipinle Ogun to egbe oselu Accord.


Adesina soro yi lojo Monde to koja yii lasiko to sabewo sawon omo egbe oselu naa nijoba ibile Abeokuta North to wa ni Sabo, Abeokuta nibi to ti so ipinu e fun ipo asoju-sofin lodun 2019 labe egbe oselu naa.

Ninu oro e lo ti so pe oun ko nidi kan ni pato toun fi yoju sawon oloye egbe naa bi ko se lati dupe gidigidi lowo won fun ise takuntakun ti won n se lati di egbe naa mu, ti won si je ko duro digbi.

O gbawon omo egbe naa lamoran pe ki won fowosowopo lati je ki ilosiwaju tubo maa de ba egbe oselu naa, ki won si maa fi ipinu ati afojusun won han fawon omo orileede Naijiria.

Bakan naa lo tun so pe sasa ni egbe oselu nipinle Ogun ti ko ni iyapa ati eleyameya ninu, sugbon to je pe Accord nikan soso legbe oselu to duro.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI