AJO ALAANU TI MO DA SILE KII SE ONA LATI FI DI OLOWO - AGBA ORO PARIWO SITA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, July 25, 2018

AJO ALAANU TI MO DA SILE KII SE ONA LATI FI DI OLOWO - AGBA ORO PARIWO SITA

Gbajumo irawo ori redio nni, Oluwashinaayomi Saubana Amodu topo awon eeyan mo si Agba Oro ti pariwo sita pe ajo alaanu toun da sile, iyen First Agba Oro Foundation kii se ona lati le fi di olowo tabi oloro ni, bi ko se lati se iranlowo fawon alailera.


Agba Oro lo soro naa nibi ayeye ojo ibi ogoji odun to se lagbegbe Soyoye, Rounder niluu Abeokuta, nibi tawon agba a sorosoro bii Olufemi Omilani to je alaga FIBAN; Olumide Awolowo; Soji Omotayo; Moruph Adegboyega, Omodo Agba; Sunday Ogunsola, Tantala; Toyin Adeniyi, Olori; atawon min in ti pe jo lati ba a sayeye naa. Nibe ni ilu mon on ka olorin nni, Alayo Singer ti dalu bole.

O ni bo tile je pe o ti le lodun toun ti ni ipinu lati da ajo naa sile, sugbon ti agbara oun ko gbe e latari ai ri iranlowo to peye, sibe oun ko ni irewesi okan lati gbagbe ipinu naa, sugbon lodun meji seyin ti won da ileese redio Family sile, ni ona si fun ajo naa.


Ninu oro e, "Ti a ba ni ka wo o, awa sorosoro ati pedepede po repete kaakiri ipinle Ogun, sugbon gbogbo wa ko le sun ka k'ori sibi han naa, erongba mi lori eto mi ti mo pe ni Atipo Laye ti wa Layi bii odun mefa bayii, sugbon ko si agbara nigba yen, afigba ti Olorun so pe asiko ti to ni nnkan bi odun meji seyin nigba ti ileese redio molebi, iyen Family FM de.

"Erongba mi ni pe awon eda kan wa ti a da ni akanda eeyan, iyen awon ti won ni ipenija ara, lati le mu inu won dun, idi ni yii ti mo fi pinu lati gbe eto naa kale fun won pe kawon naa le maa ni eto ti won ma maa gbo loto.


"Mo fe e je ki won mo pe ko si iyato laarin awa ti a pe ara wa ni Abarapa atawon akanda eeyan won yii. Awon akanda ta a jo n seto lori redio, ni mo le pe ni akanda alagbe, iyen awon to n toro owo, ninu won lati ri awon to n korin, aimoye awon to ni ise owo lowo, a maa n ran won lowo lati le je ki won da duro, ki won si kuro ninu eni to n toro owo jeun."

Nigba to n soro nipa aseyori ti won ti se ninu ajo naa, Agba Oro so pe bo tile je pe ajo naa sese pe odun kan ni, sugbon opo ise ti won ko le menuba tan ni won ti se latari ri ran awon akanda eeyan naa lowo.


O lawon kan wa tawon ti ra orisirisi irinse fun, tawon tun fun won lowo lati fi ran won lowo, bakan naa lo so pe awon ti ra ero ata, irinse aserunloso (hairdresser), geri-geri (barber) atawon min in lawon ti ra.

Bee lo so pe awon ti n gbaradi lati je kawon Amanda eeyan naa wo yara igbohunsile (studio), ki won le gbe awo orin (kaseeti) jade, lati le je kawon naa mo pe eeyan eleran-ara lawon naa.


NKAN TAWON EEYAN SO NIPA AGBA ORO

Oluwabukola Ibilola Amodu - Iyawo Agba Oro
Eeyan to tutu, to ko eeyan mora ni oko ti mo fe, iyen Agba Oro, kii fe ki iya je enikeni, paapaa awon alaini to n tiraka lati dide. O je enikan to je pe to ba ti n binu, a fi ki won fi sile lati je ki inu e wa sile, nitori pe bi won ko ba fi sile, wahala niru eni bee n wa.


Gege bi iyawo e, mo mon on daadaa, nigba ti mo maa koko mon on, ko tii maa seto pupo lori redio, o ma n wa sile daadaa, kii sun sita nigba naa, sugbon ni bayii, oro naa ti yi pada temi naa si mo nnkan to wa nidi ise to n se.


Komureedi Olufemi Omilani - Alaga egbe FIBAN
Pedepede kan ti Olorun gba fun ni Shina Amodu, Agba Oro niru asiko ta a wa yii. Oga ni Agba Oro je si iru awa bayii, sugbon nnkan to maa n jo ni loju pupo nipa e ni pe, laarin odun meji si meta seyin ni Olorun kan pinu lati gbe ori e soke ju ti tele lo. Kii baayan se ote, eyi to tun je ko pelu awon nnkan ti mo fi feran e pupo. Ko si aaye fun mi lati wa nibi ayeye ojo ibi yii, sugbon dandan lo je fun mi lati wa nibi nitori pe eeyan ti mi o le fi sere ni.


Nipa ti ajo iranlowo to da sile, mo wa jibe lojo to fi lole, iyen ajo Atipolaye (First Agba Oro Foundation), eyi to nii se pelu awon ti ara won ko pe, iyen awon to ni ipenija eya ara. Ipinu to dara ni, ti mo si wo o pe bi a ba tubo ri ninu awon eeyan wa to ba ni iru nkan bayii lokan, ki won tete se e.


Ogbeni Olumide Awolowo - Orobo
Shina Amodu, iyen Agba Oro, o ti le lodun mewaa ti mo ti mon on, mo si le fi gbogbo enu so o pe okan pataki ninu awon irawo lenu ise pedepede ni. O si tun je eeyan pataki kan ninu okan mi, nitori pe nigba ti mo n se igbeyawo mi, oun ko duro ti mi gege bi omo-iya, to si jo mi loju pupo.

Lara nnkan ti mo n so nipa Shina Amodu ni ti ajo iranlowo to gbe kale, o je eyi to dun mo mi ninu pe o tayo laarin wa, o yato si pe ka kan maa se nnkan bawon kan se n se e, ironu e yato gedengbe. O n fi ajo naa ro awon eeyan, paapaa awon alaabo-ara lagbara, ti won si ti da duro.


Moruph Adegboyega - Omodo Agba
Nigba ti mo maa koko mon on, Ado-Oro lo n je nigba naa, o ti pe gan an ti mo ti mon on, iyen nigba ti mo si wa pelu ileese redio ipinle Ogun. O fe e je pe ija la fi mo ara wa, mi o ni soro lo sibe, sugbon ti mo mo pe oro mi ti ye oun funra e. Olumide Awolowo naa pelu awon to maa m fa ija nigba naa, sugbon oro naa kii se awada. Igba to ku die ki n kuro nileewe OGBC ni mo too ri pe omo gidi ni, eeyan daadaa si ni.

Igba to di pe ileese redio Family bere, toun naa wa a darapo mo wa ni mo sese wa a ri iru eeyan to je gangan, ti mo wa a ri pe enikan to ni ebun ni, kii fe e gba pe ko si nnkan ti ko see se, gbogbo igba lo maa n gbiyanju, kii se ti imule tabi nnkan min, o maa n temi lorun ti a ba fe e se eto eleni-mehi, ko je pe emi ati e la jo maa se e.


Lojo kan ni mo pe e, ti mo si ba a soro pe ko wa maa se eto ti mo maa n se, iyen eto Awodi Oke leekookan, sugbon se lo so pe oun ko le se e nitori pe oun agbara oun ko gbe, igba yen ni mo sese wa a mo pe kii se okunrin, nitori pe eni ti ko ba le se iru eto ti mo n se. Akikanju eeyan ni, nibi to ni oju aanu de, o lowo moto, sugbon ko ra a, emi ni mo gba a nimonran pe ko loo ra moto.


Sunday Ogunsola - Tantala
Omo gidi to ni alubarika ni Agba Oro, eni ti mo nife lopolopo ni, ti inu mi si maa n dun ti m ba ti foju kan an. Mi o le ka oore to ti se fun mi tan, alaanu mekunnu ni, to si ko eeyan mora lo je. Ni ti ajo iranlowo to da sile, kii se pe o fe e fi wa ona lati di olowo repete, oju aanu to ni lo je ko da ajo naa sile, to si ti ran opo awon eeyan, paapaa awon akanda eeyan lowo. Olooto eeyan to se e fokan tan ni, ti kii si se madaru. Mino tii sakiyesi aleebu kan lara Agba Oro latigba ti mo ti mo titi dasiko yi.Sola Oniyide 
Ti m ba so pe ki n bu kere, o ti fe e to odun mewaa ti mo ti mon on bayii, ti m ba so pe ki n bere sii so iru eeyan to je, ile maa su, o si tun maa mo ba wa nibi, sugbon maa ge kuru. Agba Oro kere loju, sugbon ogbon ori e ju ojo ori e lo. O ni afojusun gidi, to si tun ko awon eeyan mora, kii se oju saaju, gbogbo awon eto lo maa n yi aye eeyan pada, ko si asadanu ninu awon eto to n se e. Kii huwa imotara-eni-nikan, o maa n ro teeyan mo ti e.

A maa n ja gan an, nitori pe ti n ba fun ni amonran nigba min in, ti ko si fe e tele, sugbon to ba ya, o tun maa pada gba si mi lenu. Ko seni ti ko ni 'sugbon', amo sa, ti Agba Oro yato. Kii binu, ko laapon, ko si feran wahala.Ogbeni Akin Balogun
Aburo mi ni Agba Oro, o ti to bii odun kan aabo seyin ti mo pade e, latigba naa ni mo ri gege bi eni to ni iwa irele, o wulo fun ara, ore ati ebi ee. Ko ri enikan gege bi omode, iteriba to ni ko se e so tan. Ti m ba gbo ipe e nigbakugba, maa sare loo da a lohun, ko si nkan to beere, bi agbara mi ba ti ka a, dandan ni ki n se e fun.


Toyin Adeniji - Olori
Mi o ti e mo ibi ti mo ti fe e bere oro nipa Agba Oro, nitori pe o je eeyan kan to ni iwa rere lawujo. O si je eni kan ti inu e mo, ti ko si feran e gidigidi, eni to ma n wa ilosiwaju eeyan ni, ti kii se oju saaju enikeni. Ipa ribiribi to ko ninu aye mi, lo je ki n mo iru eeyan to je. O ti n lo bii odun mesan an bayii ti mo le so pe mo ti mo Agba Oro, bo tile je pe ko seni ti ko ni abuda ti e, sugbon abuda e ti mo le so pe mo ri ko po rara. Kii mu eeyan sinu, kii yan odi. Tife-tife lo fi n baayan se, opolopo eko ni mo ti ko lara e, ti ko si tun n ko eko lara e titi dasiko yi.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI