O pe o: Soosi Treasure House of God bere irolagbara fawon odo l’Abeokuta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, July 2, 2018

O pe o: Soosi Treasure House of God bere irolagbara fawon odo l’Abeokuta

Lati le din ise ati osi ku, paapaa airise se awon odo lorileede Naijiria, olori ati oludasile soosi Treasure House of God to wa ladugbo Agbeloba, Abeokuta, Pasito Adeseye Senfuye ti bere irolagbara fawon odo, eyi ti yoo mu won kuro ninu ise ati osi.
 
Gege bi atejade ti alakoso iroyin fun soosi naa, Ogbeni Adeniyi Adeloye se fi to AWIKONKO leti lojo Sande to koja yi, a gbo pe ara oto ni irolagbara naa je, ati pe lati mu erin pa ereke ogunlogo awon odo ni eto naa wa fun, paapaa ki edinku de ba isoro airise se.

Eto iforukosile naa ta gbo pe gbogbo odo kaakiri orileede Naijiria ni won i anfaani lati loo forukosile, nitori pe ojo Satide to koja yi, iyen ogbon ojo osu kefa si ojo kokanlelogun osu yi ni eto iforukosile yoo fi waye ninu ogba soosi naa to wa ni 177, Quarry Road, Agbeloba, Abeokuta.

Nigba to n gba enu Pasito Senfuye soro, Ogbeni Adeniyi so pe kii se pe Pasito naa dee de gbe eto yi kale lati se iranlowo fawon odo, sugbon lati le mu edinku ba airise se awon odo, ki opo odo to wa ni orileede yi le ri nnkan maa fi pa owo da lo mu ipinu yi wa.                                          

O ni ona kankan soso lati le mu idagbasoke ba orileede yi ni lati ro awon odo lagbara, nitori pe ijoba apapo orileede yi naa n gbiyanju lati je kawon odo ri ise se.
Bakan naa lo tun je ko di mi mo looto lawon odo je ojo iwaju orileede yi, ti won si tun se pataki daadaa, nitori naa lo se je pe ojo iwaju won je oun logun pupo, toun si gbodo tete wa ona abayo si isoro won.

Bee lo tun so pe won yoo ko awon odo nise owo, bee naa ni won yoo tun fun won lowo ti won yoo fi bere ise won.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI