Igbeyawo odun marundinlogbon tuka si kootu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, July 2, 2018

Igbeyawo odun marundinlogbon tuka si kootu


E so fun oko mi pe ko k'eru e jade nile mi – Iyaale ile
Bi ere bi awada loro naa ri nile ejo kokokoko to wa ni Ake Abeokuta lojo Tusde ose to koja, ko da a, ko seni to gbo biyaale ile kan to poruko ara e ni Muniratu Adeleye se n soro niwaju awon adajo pe ki won ba oun pa a lase pe ki oko oun ko gbogbo eru e jade kuro nile toun ko, nitori pe ibe lawon jo n gbe, ati pe ki won foun ni olopaa lati ma le je ki oko oun lu oun lasiko to ba n ko eru e naa.
Bo tile je pe oko Muniratu, Ogbeni Isikilu Alani Adeleye ti won ni moto awon to n ja oja kaakiri lo n wa ko yoju si kootu leemeta otooto ti won f'iwe pe pe koun naa wa a so tenu e, nitori pe o seese ko je pe iro niyawo e n pa mo, sibe illejo tu igbeyawo naa ka.
Nigba to n ro ejo enu e, to tun fi Kuraani bura nile ejo, Muniratu so pe Oko oun ko jawo ninu awon iwa aibikita to n hu soun atawon omo ninu ile, ko da a to si tun je pe bee naa lo n se pelu awon ebi e.
Iyaale ile naa to so pe merin loun bi foko oun ni “Agidi oko mi ti po ju, kii gbo, kii gba ni. Ojoojumo lo n fa wahala lai nidii. Latigba ti mo ti n fun ni leta pe won n pe ni kootu, nnkan to n so ni pe oun ko le wa a kawo po'yin rojo ni kootu lailai.
“Ile mi ti mo fi owo ara mi ko la jo n gbe, ko ra bulooku kan fun mi, depodepo pe yoo ronu lati toju mi. pelu pe o n gbe inu ile mi lofee, o tun maa n lu mi bii ki n ku. Oro e ti su mi. e jowo Oluwa mi, e ba mi le e jade, ko si ko gbogbo eru e ni kiakia. Mi o le ba a gbe mo.”
Aare ile ejo naa, Oloye Akande O. O ati igbakeji e, Onarebu Arabinrin Majekodunmi H. I so pe ko si nnkan tawon tun le se ju pe kawon tu igbeyawo naa ka lo niwon igba ti Isikilu ko ti yoju lati wa a so tenu, to si dabi eni pe ko nife si ejo naa.
Won wa pase pe kigbeyawo naa tuka lesekese, bee ni won so pe ki baale ile naa ko eru e kuro ninu ile naa, ati pe ko gbodo ko lati maa se eto e to ba ye lori awon omo ti won jo bi. Bakan naa ni won so fun Muniratu pe bi oko e ba fa wahala lasiko to ba n ko eru e, ko mu iwe ase ile ejo lo si ago olopaa to ba sunmo on, ki won le tete gbe igbese.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI