SOOSI MFM FEE BERE AAWE ATI ADURA ALAADORIN OJO LOSU KEJO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, July 7, 2018

SOOSI MFM FEE BERE AAWE ATI ADURA ALAADORIN OJO LOSU KEJO

Alakoso ati oludasile soosi, Ori Oke Ina ati Ise Iyanu (Mountain of Fire and Miracles Ministries, MFM), Dokita Daniel Kolawole Olukoya ti kede sita pe aawe ati adura alaadorin ojo (70days fasting and prayer) ti won maa n se lodoodun ti odun 2018 yoo bere ninu osu kejo.


Nibi ipade adura Agbara Gbodo Paaro Owo (Power Must Change Hands) olosoosu ti won maa n se lojo Satide akoko ninu osu ni Dokita Olukoya ti kede eto adura naa, eyi to waye lojo Satide onii.

O so pe ojo karun osu kejo to m bo yi ni eto naa yoo bere, eyin ojo Monde to ba tele eto adura Agbara Gbodo Paaro Owo ti osu kejo naa, ti yoo si se opo awon eeyan kaakiri agbaye, paapaa awon omo ijo naa lanfaani to po.

Dokita Olukoya je ko di mi mo pe iwe adura ti won yoo lo fun eto adura naa ko ni pe e jade sita fun ri ra, nitori naa kawon eeyan maa gbaradi lati ra a ni iye owo ti ko nii pa won lara.

Oludasile soosi MFM naa tun tenu mon on pe o se pataki fawon omo ijo naa lati kopa ninu eto aawe ati adura naa, nitori pe fun anfaani ara won ati orileede won lo wa fun.

Bakan naa nigba to n soro lori eto ipade adura Agbara Gbodo Paaro Owo osu kejo, o ni eto naa yoo kun fun opolopo adura lojo naa, nitori pe aadorin (70) adura lawon yoo gba lojo naa, nitori naa kawon to ba fe e kopa mu aworan (Foto) won pelu ti molebi won dani.

O so pe ori foto naa ni won yoo gba awon adura aadorin yi si, ti won yoo si ipa awon adura naa lesekese.

Bee lo tenu mon on pe ki won ko ebe adura mejila (12 Prayer Points) lori awon nnkan ti won fe ki Olorun se fun won ki odun 2018 yi too pari bi won ba ti n bo lati le bawon gbadura sii.

Nigba to n waasu lori akole to pe ni Kikede Isinku (Obituary Announcement), Dokita Olukoya so pe nnkan to maa n pa ijo ni aile gbadura gege bi Olorun ti fe, ati pe onigbagbo kekere ko maa n gbadura iseju merin lojumo, iyen tiru onigbagbo bee ba ti n e gbadura.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI