WON FI FAYOSE SELEYA NIPINLE EKITI, WON SIN EGBE OSELU PDP - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, July 15, 2018

WON FI FAYOSE SELEYA NIPINLE EKITI, WON SIN EGBE OSELU PDP

...Bee ni Gomina Amosun Ba Fayemi Sajoyo

Titi di bi e ti n ka iroyin yi lowo lawon omo egbe oselu APC nipinle Ekiti, paapaa kaakiri orileede Naijiria si fi n ba adije sipo gomina ipinle naa labe egbe oselu naa, Dokita Kayode Fayemi to gbegba oroke nibi idibo gomina to waye lojo Satide to koja yii.


Bawon kan se n fi Gomina Peter Ayodele Fayose se eleya, bee lawon kan n so pe egbe oselu PDP ti di ohun igbagbe patapata nile Yoruba pelu bo tun se je pe Fayemi lo jawe olubori lopin ose to koja yi.


Aworan kan to te AWIKONKO lowo lati ri bawon kan se n sin egbe oselu PDP to je egbe alatako to duro daadaa, ti won si n korin pe o digbose patapata.

Gomina ipinle Ogun, Ibikunle Amosun ti ba Dokita Kayode Fayemi sajoyo fun ti bi won se kede e gege bi enk to jawe olubori lasiko idibo gomina to waye lojo Satide to koja yi.


Asiri to tu si AWIKONKO lowo je ko ye wa pe Gomina Amosun gan an lo fe e je gege bi igi leyin ogba fun bi Kayode Fayemi se wole gege bi gomina labe egbe oselu APC.


Eyi lawon Foto Gomina Amosun pelu awon Komisana e nipinle Ogun, to fi mo awon amugbalegbe e nibi ti won ti n ki Gomina tuntun naa ku oriire.
PÍN-IN KÁÀKIRI