ASIRI AKEKOO FUNAAB TO JAWON AKEKOO EGBE E LOLE TU - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, August 22, 2018

ASIRI AKEKOO FUNAAB TO JAWON AKEKOO EGBE E LOLE TU


Won ni ojo gbogho ni ti ole, ojo kan soso ni tolohun, eyi gan an lo lo nibamu pelu bowo se te gendekunrin kan tj won loo feran lati maa pa awon akekoo egbe lekun lo, nipa ji ji eru won gbe salo.

Gege ba a se gbo, gendekunrin naa ta a ko tii mo oruko e titi dasiko ta a sakojopo iroyin yi tan la gbo pe okan lara awon akekoo ileewe faisiti ti use ogbin, iyen FUNAAB ni.

Won ni asiko tawon akekoo egbe e toku ba ti lo si kilaasi, loun maa n rapala loo ja ilekun yara won, ti yoo si ko won leru bii owo, ounje, aso, bata atawon nnkan min in salo.

Gendekunrin naa ti won ni eka ikekoo FNG lo wa la gbo pe ile awon akekoo, iyen hostel lo n gbe ladugbo Camp, Abeokuta, to si je pe orisirisi ile lo ti loo fo lati ko won leru salo.

Sugbon lojo Tusde ose to koja yii, ni won lasiri e tu sawon onile kan to sese loo fo lowo, asiko ti won lawon akekoo n se idanwo saa yi lowo, ti ko senikeni nitosi ni won loo tun lo anfaani e ju.

Nigba tasiri e maa tu, kani awon akekoo egbe e to n gbe inu ilegbe awon akekoo egbe e sun asunpara ni, o see se ko tun ri eru won ni gbe salo kasiri e ma si tu si won lowo.

Won lawon akekoo ti won ko ni idanwo lojo naa lo muu, a gbo pe ose to lo lohun lo loo ko won leru ninu ile naa atawon ile meji min in, tawon yen si bere sii gbe se epe rabanderabande.

Ariwo irin kekere kan ti won loo fe e fi ja ilekun wonu yara to ti fe e ko eru ni won lawon to wa nitosi gbo, p si ti wole tan ki won too lo ka a mo, to si bere sii bebe fun idaraji lesekese towo te e.

Bi won ni won se fe maa luu lawon ti aanu e se e ti ni ki won loo fa le awon olopaa tabi awon eso alaabo ileewe naa lowo lati le fi Iya to to je e labe ofin.

Gbogbo akitiyan lati ba agbenuso awon olopaa, Abimbola Oyeyemi soro ko le fidi e mule lo ja si pabo titi ta a fi sakojopo iroyin yi tan.

PÍN-IN KÁÀKIRI