Kii se pe won sese bere
wahala naa, o ti le lodun die seyin ti won ti wa lenu e sugbon o dabi pe akoko
yii ni won fee yanju gbogbo e patapata, ti won si fe e fo oro naa loju
yanna-yanna.
Oloye Gbadamosi |
Awon araalu Apena ti
won wa ni Obada Oko nijoba ibile Ewekoro nipinle Ogun ni won ke si Olu Obada
oko, Oba Olufemi Solaja pe ko tete fi ile awon sile ti ko ba fe wahala nitori
pe alejo lawon babanla e je lodo awon.
Baale ilu Apena, Oloye
Abiodun Gbadamosi so pe baba awon to n je Sangodiya-Koole lo te ilu Apena do,
ati pe oja ni Oba oko.
O salaye pe lodun 1918
ni Oba Gbadebo akoko wa si oja si Obada. Oba wa da oja sile ni oko ni won so di
Obada Oko to n je titi di akooko yii.
O fi kun oro e pe lati
gba ti won ti ni ki won maa f’oba je ni Obada Oko lawon ti wa lenu e, O ni
Mufutau to koko je Oba, omo Igbore ni, tawon gbe e lo sile ejo, ti adajo si
pase pe ko ma se pe ara e ni Oba mo.
Leyin igba naa lo so pe
won tun gbe awon pada lo sile ejo sugbon tawon alagbara lo agbara le awon lori,
ori oro naa lo so pe awon wa ti Oba naa fi ku.
Baale Apena tun so pe
kaka ki won gbe ipo Oba naa fawon, alejo ni won tun fi j’oba iyen Oba Solaja ti
won lo wa lati Erunbe niluu Abeokuta, idi niyi ti gbogbo omo ilu se fimosokan
pe ki Oba naa kuro lori ile won.
O lawon ti ko leta si
Alake tile Egba, Oba Adedotun Gbadebo, bee naa lawon ti ko iwe sileeese to n ri
soro ijoba ibile ati oye jije nipinle Ogun ati Gomina Ibikunle Amosun lati tete
ba won da sii, ko too pe ju.
O lawon eeyan Apena je
ebi to nifee si alaafia nitori e lawon se gbe awon igbese tawon n gbe naa, yato
si pe oro naa ti wa nile ejo bayii.
Ninu oro Alagba Akingbade
Jibowu to pe ara e ni okan lara awon olori ebi Oba to wa lori oye naa, o so pe
loooto alejo lawon ni Obada, o ni Erunbe ni Abeokuta lawon ti se wa, o ni Apena
lo ye ko ma a joba ni Obada Oko.
Sugbon Olu Obada ti so
pe ko soro ninu gbogbo nnkan ti won so ati pe won kan fee daluru ni. O ni awon
ajagungbale lawon to fee da wahala sile niluu.