E TETE LOO GBA KAADI IDIBO ALALOPE, PVC YIN O - DIAKONI MOFOLUKE SOREMEKUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, August 18, 2018

E TETE LOO GBA KAADI IDIBO ALALOPE, PVC YIN O - DIAKONI MOFOLUKE SOREMEKUN

Alaga ijoba ibile idagbasoke Ilugun, Diakoni Arabinrin Mofoluke Soremekun ti rawo ebe sawon omo orileede Naijiria, paapaa awon omo ipinle Ogun pe ki won tete loo gba kaadi idibo alalope, PVC won ki gbedeke ojo ti ajo eleto idibo, INEC fi sita too pe.


Diakoni Soremekun lo soro yi lonii lakoko to loo sabewo sawon agbegbe ile idibo ti won ti n foruko sile fun kaadi idibo alalope naa, iyen awon agbegbe bii Alagbagba to wa nijoba ibile Odeda, iyen woodu karun un; Efon, to wa ni woodu karun un ati Ojebiyi/Owu to wa ni woodu kerin.


O ni bi idibo apapo odun 2019 se n sunmo etile, o se dandan, o si tun se pataki ki gbogbo awon to ba n fe ilosiwaju orileede lati loo foruko sile fun kaadi idibo alalope, PVC won ko too pe ju.


Soremekun ni lai si kaadi idibo yii, ko seni to le lanfaani lati dibo fun eni to ba wuu lokan, ayafi ti won ba gba kaadi naa.


Nigba to n gboriyin fun ajo eleto idibo latari bi won se sun ojo ti asiko iforukosile yoo pari siwaju, Diakoni Soremekun so pe inu oun dun pupo fun ipinu ati igbese ajo INEC, nitori pe opo awon eeyan ni won si n tiraka lati foruko sile.


Bee lo tun wa a je ko di mi mo pe irin-ajo abewo naa yoo tun tesiwaju bi awon osise eleto idibo naa se n lo fun isinmi olose kan fun ti ayeye odun Ileya to n bo lona.
  

Wonyii ni die lara foto awon abewo naa:

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI