ILEYA: E JE KA GBA ALAAFIA ATI ISOKAN LAAYE - ONAREBU KAYODE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, August 21, 2018

ILEYA: E JE KA GBA ALAAFIA ATI ISOKAN LAAYE - ONAREBU KAYODE

Onarebu Kayode Oladipupo ti gba awon omo orileede Naijiria lamonran fun ayeye odun Ileya to n lo lowo yi pe kawon elesin gbogbo lorileede yi, paapaa awon Musulumi gba alaafia ati isokan laaye lati le mu itesiwaju ba wa.


Adije sipo omo ile igbimo asoju-sofin ipinle Ogun labe egbe oselu ACCORD lodun 2019, Onarebu Oladipupo lo soro naa laaro yi ninu atejade to fi ki awon omo leyin Anobi ninu esin Islam.

O so pe ohun kan soso to le mu ki orileede tesiwaju, ko si tun ni idagbasoke alailegbe ni bawon omo orileede naa ba le yago fun eleyameya, ki won si gba isokan ati alaafia laaye ninu ohun gbogbo.

Gbajumo onisowo naa to filuu Abeokuta sebugbe ninu oro e naa lo tun ti so pe adura ni opakutele idagbasoke fun orileede, nitori naa kawon elesin Islam ma se dake adura ninu adura won bi won ba a lo kirun ni Yidi.

Ninu oro e, o so pe "Mo ni ayo lati ba awon omo leyin Anobi, iyen awon Musulumi yo fun ti ayeye odun Ileya to wole de yi. Mo gbadura pe ti odun to m bo yoo ba wa laye pelu ogo Olorun.

"Ma a fe e fi asiko yi dupe lowo gbogbo omo orileede yi pelu ifowosopo won pelu ijoba orileede Naijiria labe Aare Muhammadu Buhari. E je ka mo pe lai so alaafia ati isokan, ko le si idagbasoke ati ilosiwaju.

"Nitori naa, e je la gba alaafia ati isokan laaye nitori pe ohun nikan lo le je ki ilosiwaju de ba wa. Bakan naa ma a gba awon omo orileede yi lamonran pe ki won tete loo fi asiko yi gba kaadi idibo alalope, PVC won pelu bi ajo INEC se ti fi kun ojo idibo."

Nigba to n dupe lowo ajo eleto idibo, iyen INEC fun bi won se sun ojo ti gbigba kaadi idibo alalope, PVC naa yoo dopin, bee lo ro awon omo orileede Naijiria pe ki won lo anfaani naa la ti tete loo sawon agbegbe iforukosile ki asiko to o lo.

Onarebu Oladipupo ni kaadi idibo alalope, PVC naa nikan agbara tawon omo orileede yi ni lati yan eni to ba wu won, paapaa awon odo sipo lodun 2019.

Siwaju sii lo gboriyin fun Aare orileede yi, Ogagun Muhammadu Buhari pelu awon ise akanse to n lo lowo kaakiri orileede yi.

Bakan naa lo tun gbe osuba kare fun Gomina Ibikunle Amosun fawon idagbasoke to ti mu ba ipinle Ogun laarin odun meje isejoba e.

PÍN-IN KÁÀKIRI