Ẹgbẹ oṣelu ADP ni ki Ambọde sanwo oṣu awọn agbalẹ oju titi - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, August 29, 2018

Ẹgbẹ oṣelu ADP ni ki Ambọde sanwo oṣu awọn agbalẹ oju titi

Ẹgbẹ oṣelu alatako nipinlẹ Eko, Action Democratic Party, ADP, ti ke si Gomina Akinwumi Ambọde tipinlẹ Eko, lati sanwo oṣu awọn agbalẹ oju popo ti wọn ṣe iwọde lọjọ meloo kan sẹyin, wọn ni ki i ṣe nnkan to bojumu ni ati pe wọn fẹẹ maa fi ẹtọ awọn eeyan naa dun wọn.


Gẹgẹ bi atẹjade ti alukoro fẹgbẹ naa, Ọmọọba Adelaja Adeoye fi sita lo ti sọ pe o jẹ ẹdun ọkan bii ileeṣẹ Visionscape ati ijọba ipinlẹ Eko ṣe n ṣawọn oṣiṣẹ naa, bi igba ti wọn fara ni awọn araalu lẹgbẹ oṣelu ADP naa ka a si.

Wọn fẹsun kan Gomina Ambọde lori bo ṣe gbe awọn oṣiṣẹ agbalẹ oju popo naa kuro labẹ PSP ti wọn n gbiyanju lati  jẹ ki Eko wa ni imọtoto, ti wọn si gbe wọn sabẹ Visionscape ti wọn kuna patapata lori iṣakoso imọtoto nipinlẹ naa.


Adelaja tun ṣalaye pe latigba ti Gomina ti ṣagbekalẹ ileeṣẹ tuntun naa ni idọti ti n pọ si kaakiri ipinlẹ Eko bẹẹ lo si jẹ pe awọn oṣiṣẹ ti wọn gba lati maa ko ilẹ ati idọti, wọn kọ, wọn ko fun wọn lowo oṣu, o ni ki i ṣe nnkan to bojumu rara.

O ni itiju nla lo jẹ fun ijọba ipinlẹ Eko pe awọn agbalẹ oju popo ṣewọde lọọ si Alausa pe wọn je awọn lowo oṣu to pọ. Eyi to tumọ si pe igbe aye awọn araalu ko jẹ ijọba logun mọ, niwọngba ti wọn ba ti n jẹ iru awọn eeyan bẹẹ lowo oṣu, Ko si igbagbọ mọ ninu ijọba APC nipinlẹ Eko.


Wọn nigba tileeṣẹ Visionscape ti kuna lati jẹ ki imọtoto wa nipinlẹ Eko, ohun to dara ni pe kijọba fagile ileeṣẹ naa nitori inu awọn araalu ko nii dun ki wọn maa nawo ti ko ni itumọ lori ileeṣẹ ti ko mu aṣeyọri bawon.

Wọn wa rọ Ambode lati ri i pe won san gbogbo owo ti wọn jẹ awọn eeyan naa, nitori ohun ti wọn ṣiṣẹ le e lori ni.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI