Wọn ni Kẹmi Nelson di ẹru jẹjẹ sigboro Eko - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, August 29, 2018

Wọn ni Kẹmi Nelson di ẹru jẹjẹ sigboro Eko

...Awọn tọọgi lo ko lọọ dena Jumọke Ọkọya Thomas

Ṣe lọrọ di bo-o-lọ- ko- ya- fun mi lọjọ Aje, Monde, ana an, nigba ti Oloye Kẹmi Nelson to jẹ alakoso fun ileeṣẹ NSITF ṣadeede yawọ ọfiisi ẹgbẹ APC to wa ni Acme, niluu Eko pẹlu awọn tọọgi mẹfa ti wọn si digbo lu Arabinrin, Ọnarebu Jumọke Ọkọya Thomas.


Bi ki i ba si ṣe ọpẹlọpẹ Ọlọrun, ọtọ ni nnkan ti a ko ba maa wi bayii, nitori bawọn tọọgi ọmọlẹyin Kẹmi Nelson ṣe din dundun iya fun amugbalẹgbẹ ẹ obinrin naa iyẹn Alaaja Abiọdubn to si di nnkan ti wọn gbe lọọ si ọsibitu nibi to ti n gba itọju.

Jumọke Ọkọya Thomas yii ni wọn sọ pe oun lo jẹ aṣaaju awọn obinrin ninu ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Eko nigba ti Kẹmi Nelson to ti wa nipo naa tẹlẹ ti ni igbega lọọ si tawọn obinrin oloṣelu ẹgbẹ ọhun nilẹ Yoruba ṣugbọn ti wọn ni ko tẹ ẹ lọrun to si n ba ẹni to wa nibẹ fa a wahala gidi..

Gẹgẹ bi iwadii oniroyin wa, ibi ipade pẹlu alaga ẹgbẹ oṣelu naa, Tunde Balogun ni wọn wa lọjọ naa ti wọn ni Kẹmi Nelson atawọn tọọgi ẹ yii fi yawọ ibẹ. Wọn ko beṣu bẹgba, ti ọkan ninu wọn ti wọn pe orukẹ ẹ ni Ayọ Ali Balogun fi lọ baa Okoya Thomas, to si sọ fun un pe ko sọ ara ẹ daadaa.


Ere lawọn to wa nibi ipade naa kọkọ pe e ti wọn si ya ẹnu wọn pe ki lo ṣẹlẹ, pẹlu gbogbo bi wọn ṣe ni tọọgi yii n sọ, wọn lobinrin naa ko sọ nnkan kan ti wọn lo si fi ọfiisi silẹ fun un lati yago fun eṣu.

Ṣugbon nigba ti eṣu Ayo Alli Balogun ri i pe iyẹn ko ṣe e ṣe, lo bọ sita to si n wa ibi ti amugbalẹgbẹ obinrin naa wa ni nibẹ lo ti lọọ lu obinrin naa nilukulu eyi to mu ki ẹjẹ maa jade ni ara ẹ ti wọn si sare gbe e lọ sile iwosan.

Ohun to n ṣe awọn to wa nibẹ ni kayefi naa ni pe kin ni nnkan to le ṣẹlẹ ti obinrin to pe ara ẹ ni aṣaaju awọn obinrin APC nilẹ Yoruba ṣe di ẹru jẹjẹ lọsan an gan-an to fi ko awọn tọọgi mẹfa wọnu ọfiisi ẹgbẹ naa.


Ohun ta a gbọ ni pe wahala naa ti bẹrẹ nigba ti Jumọke Thomas di aṣaaju ẹgbẹ obinrin naa nipinlẹ Eko ṣugbọn ti Kẹmi Nelson to ti wa nibẹ tẹlẹ kọ ọ lati fa iṣẹ le e lọwọ, bẹẹ ni wọn lo si kọ lati kuro ni ọfiisi to jẹ ti obinrin tuntun ti wọn ṣẹṣẹ yan naa.Wọn ni gbogbo ọna lawọn to sunmọ awọn mejeeji ti sa lati ri i pe wọn yanju aawọ naa ṣugbọn ti wọn ni Kẹmi yari pe oun ko ni i gba, oun yoo mu nnkan le koko fobinrin naa.

Awọn kan sọ pe ṣe ni obinrin naa, Kẹmi fẹẹ di alaṣe to jẹ pe oun lo fẹẹ maa fi ẹni to ba wu u sipo naa lẹyin ẹ, ibi tọrọ naa yoo wa yọri si, ko sẹni to le sọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI