ETO 'KA JO SE' LATEEF OGUNJOBI TI YI PADA O - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, August 10, 2018

ETO 'KA JO SE' LATEEF OGUNJOBI TI YI PADA O

Bi e se n ka iroyin yi, eto ori redio ti okan lara awon gbajumo sorosoro nipinle Ogun, iyen Ogbeni Lateef Ogunjobi to maa n se nileese redio Paramount 94.5FM ni gbogbo ojo Tusde ti yi pada bayii.


Fawon to ba n gbo eto naa ti won pe ni "KA JO SE" daadaa, gbogbo ojo Monde laago meta si meta aago osan lo maa n waye tele, to si je pe ko seni to n gbo eto naa ti kii kan saara si Lateef Ogunjobi tawon ololufe e tun mo si Akanda Eledumare fun ise opolo.

Gege bi iroyin yo te AWIKONKO lowo lai pe yi se so, ni bayii, gbogbo ojo Isegun Tusde laago kan aabo osan ni yoo maa waye nileese redio naa.

Bi a ba n so nipa awon irawo sorosoro ti Olorun gba fun, tawon eeyan si n gbadun daadaa, odu ni Lateef Ogunjobi, Akanda Eledumare, kii sai mo f'oloko.

Ko si seni to n gbo awon eto e, ti kii fe e gbe ipolowo fun nitori bo se ni ero repete se maa n tele e.

Fawon to ba fe e ba Akanda Eledumare soro lori foonu, yala fun ipolowo tabi alaye lekunrere, nomba 08106281217 ni ki e pe.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI