GBAJUMO SOROSORO DI BABA IBEJI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, August 11, 2018

GBAJUMO SOROSORO DI BABA IBEJI

...won lowo oga e, Jigan lo mu

Bo tile je pe iro ati aheso lasan ni opo awon to gbo pe okan lara awon gbajumo sorosoro ori redio nni, Ogbeni Abass Adefulu tawon eeyan mo si Atunbi Pedepede tiyawo e bimo lai pe yi di baba ibeji, sugbon ti oro naa pada wa a di otito bayii.


Gege ba a se gbo, ojo Monde to koja yi, iyen ojo kefa osu yii la gbo pe iyawo Abass, iyen Arabinrin Ayodele Adefulu bi omo tuntun, tawon omo naa si je ibeji.

Iroyin to te AWIKONKO lowo lori awon oro to n lo kaakiri igboro nipa okunrin to maa n se eto kaakiri redio lawon ipinle bii Eko, Ogun ati Oyo ni pe iro lo n pa, zigi lasan ko fe e fi se fawon eeyan, paapaa bo tun se gbe foto awon ibeji sori eka ayelujara, Facebook pe ki won ki oun ku oriire.

Idi tawon eeyan ko fi tete gba gbo nipa iroyin naa ni bo se je pe ibeji ni oga Abass Adefulu, iyen Aare ana fegbe sorosoro lorileede Naijiria, Oloye Yemi Sonde tawon eeyan tun n pe ni Jigan Akala bi.

Won ni se lo fe e fi je kawon eeyan mo bo se nife oga e, Jigan si lo je koun naa dogbon so pe ibeji niyawo oun bi.

Nigba ti oro naa pada di otito mo awon ti ko gbogbo lowo, ni won bere sii beere lowo awon to sunmo gbajumo sorosoro tawon eeyan n gba ti e naa lati beere lowo won pe se looto ni, tawon yen naa si n fidi e mule fun won.

Eyi to tun wa a je kawon to mo okunrin naa to maa n kilaasi (class) ara e laarin awon egbe e maa fe e fi se yeye ni bo se je pe obinrin meji lawon omo ibeji naa tun je.

Won ni okunrin to da yato gedengbe nipa agbekale oro, paapaa to ba loo sise MC lode ariya ko mo ere e se lori beedi bii ti oga e, Jigan latile je ki okan ninu awon ibeji naa je okunrin, tabi kawon mejeeji je obinrin.


Fawon to ba mo Yemi Sonde daadaa, won a mo pe ibeji tiyawo e bi fun un, okunrin meji ni won, toun naa si n fombu nigba naa pe okunrin mesan an to le loun.

Bee ni won tun so pe ere ori beedi ti momi an dadi (Mummy and Daady) lo mon on se ju, idi ni yii tiyawo e fi yii mole lati bi obinrin meji leekan soso.

Sugbon sa o, ko si nnkan meji to n lo kaakiri igboro nipa Atunbi Pedepede bi ko se bawon eeyan se n kii fun ti ibeji naa.

AWIKONKO naa n fi asiko yi ki gbajumo sorosoro tawon eeyan n gba ti e kaakiri ile Yoruba to fi mo oke okun, iyen niluu awon Oyinbo lohun pe o ku owo ninu omi.

Ojo Monde to n bo yi, iyen ojo ketala ni eto ayeye isomoloruko yoo waye ni ojule kinni, adugbo Igboore Odunmbaku, opopona Ijeja, Obada, ipinle Ogun (No 1, Igboore Odunmbaku Street, along Ijeja Road, Obada, Ogun state).

Aago kan osan ni eto naa yoo bere, fun alaye lekunrere, e pe Abass Adefulu sori foonu e: 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI