Ajo kan to n ri si awon omo ti ko niya ti won wa
labe Jama’atul Izalatul sabewo sile awon omo ti ko niya to wa ni Babusalam,
GRA, Ikeja fun ti ayeye odun ileya nibi ti won ti febun tore fawon to wa nibe
lati le je ki inu tawon naa fodun to koja lo yii.
Awon ebun bii aso, bata, fila atawon nnkan mi in
ni won fi tore fawon aadota omo ti ko niya nibi ayeye. Won lawon se eyii ki
awon eeyan naa le mo pe ara kan naa ni won ati pe awon tun se lati ran won
lowo, pelu ileri pe loorekoore awon yoo maa yoju si won.
Ninu oro Mallam Hassan Idris to je olori awon omo
ti ko niya naa, o dupe lowo ijo Jama’atul Izalatul fun iranlowo ti won se naa
bee lo tun wa ke si awon eleyinju aanu lorile ede yii lati tubo maa dide
iranlowo fawon to ku die kaato lawujo.
O ni nnkan Pataki to je awon logun ju fawon omo
naa ni eto eko ati idanilekoo loorekoore, o lawon ti fun opo awon omo to wa
labe won yii lanfaani iru awon nnkan bee lati ileewe alakoobere titi de
yunifasiti