NITORI KASAMU: PDP KO IWE SAWON OLOPAA OTELEMUYE ATI INEC - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, August 4, 2018

NITORI KASAMU: PDP KO IWE SAWON OLOPAA OTELEMUYE ATI INEC

Awon alakoso egbe oselu Peoples Democratic Party niluu Abuja ti ko iwe sawon olopaa otelemuye ati ajo eleto idibo, INEC nipinle Ogun lati le je ki won mo pe Seneto Buruji Kasamu atawon meta kan ti won le danu kii se omo egbe won mo.


Ninu iwe naa ti eda e the AWIKONKO lowo lai pe yi, won fi ye wa pe ojo kinni osu yi, iyen ojo Wesde to koja yi ni won ko iwe naa lati le fi to won leti, ati pe ki won le mo pe awon eeyan naa kii se omo egbe oselu won mo.


Be o ba gbagbe, ojo Tosde ni Seneto Buruji Kasamu, Enjinia Adebayo Dayo to je alaga igun keji egbe naa atawon meji to ku so pe ko seni to le yo awon kuro ninu egbe oselu naa pelu ase tile ejo pa fawon.
No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI