Pupo ninu awon omo egbe oselu PDP ni ekun Ogun West ati Ogun Central ni won ti so pe ko seni meji tawon fe e tele gege bi adije sipo gomina ipinle Ogun ninu egbe naa lodun 2019 bi ko se Onarebu Oladipupo Adebutu.
Won ni idi tawon fi fe e tele ko seyin bi Onarebu Oladipupo Adebutu tawon eeyan tun n pe ni LADO bi ko se awon iwa aanu, ife ati ilosiwaju omonikeji e to maa n wa, ti kii sii soju saaju enikeni.
AWIKONKO gbo pe Onarebu LADO ti alaga igun keji egbe oselu naa, Onarebu Sikirulai Ogundele lewaju e loo bawon omo egbe naa lai pe ni won so pe o loo lati wa ojurere awon eeyan.
Lara awon ta a gbo pe won tun rawo ebe sawon omo egbe oselu naa pe ki won sagbateru Onarebu LADO bi idibo ba de ni igbakeji gomina ipinle ana, Alaaja Salmot Badru ati Oloye Zaccheous Oyekunle.
Eyi ni die lara awon foto bi ipade naa se lo sii.
No comments:
Post a Comment