O MA SE O: TIRELA TEEYAN PA L'OTA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, August 22, 2018

O MA SE O: TIRELA TEEYAN PA L'OTA


Ariwo ikunle abiyamo lo gba enu awon ara agbegbe Owode, Ota kan laaro ojo Abameta Satide to koja lohun nibi ijamba tirela, boosi akero atawon moto min in, to se awon eeyam lese, tenikan si gbagbe soda sorun alakeji.

Ohun ta a gbo ni pe ni nnkan bi aago mefa ku oseju ni tirela IVECO ti nomba idanimo e je XB190MLF ni ijani e ja sonu lori ere, gbogbo bi eni ti won loo wa tirela naa se n gbiyanju lati ma da wahala sile, to ja so pabo, to si loo kolu boosi akero atawon moto marun min in.

Lesekese ni agbero, iyen conductor boosi naa ti won loun n pe ero sinu moto lowo ti ku, tawon eeyan repete si farapa yannaayanna.

Agbenuso fawon eso oju opopona, TRACE, Ogbeni Babatunde Akinbiyi fidi e mule pe awon lawon gbe oku okunrin naa lo si mosuari jenera ti Ota, tawon to ku si wa nibi ti won ti gba itoju. O tun je ko ye wa pe awon ti gbe awon moto naa lo si ogba ileese FRSC Ota tawon si ti fa awako tirela naa lo si tesan olopaa Ota.

Ninu iroyin min in la tun ti gbo pe tirela nla kan naa ti te obinrin kan ti won loun ati oko e jo n lati isooru pa laaro ojo Satide Bakan naa.

AWIKONKO gbo pe ijanu tanka elepo kan naa ta ko tii mo nomba idanimo e dasiko ta a sakojopo iroyin yi tan lo ja sonu lojiji, to si loo kolu obinrin naa lrgbe titi.

Lesekese la gbo pe obinrin naa ti ta teru nipa. Awon TRACE naa la gbo pe won gboku lo si mosuari jenera to wa ni Ota

PÍN-IN KÁÀKIRI