OWO OLOPAA IPINLE OGUN TE ORE META TO N SOOWO IGBO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, August 22, 2018

OWO OLOPAA IPINLE OGUN TE ORE META TO N SOOWO IGBO

Pakopako lawon ore meta kan ti won ni won ko nise meji ju igbo tita lo n wo nigba towo olopaa ipinle Ogun te won lojo Wesde ose to koja lohun ni opopona ilu Benin siluu Sagamu.

Awon meteeta
Frank Osai, eni odun mokandinlogoji(39); Elvis Okuse, eni odun meedogun(25) ati Kelvin Ogagaoghene toun je omodun merinlelogun (24) lawon odaran naa, ko da a, ta a tun gbo pe awon ni won maa n ran lati gbe ohun ija oloro lo lati ilu Benin si Eko.

Gege ba a se gbo, ko din ni ogoji baagi to je pe igbo bii Nicotin, Marijuana atawon min in lo kun inu e ni won gba lowo won lakoo towo te won, ti won si n bebe pe ki won se won jeje.

Ohun ta a gbo pe ni pe iluu Benin ni won ti n ko awon eru naa lo si niluu Eko ko too di pe awon olopaa SARS loo dena de wpn, lati rowo to won.

Nigba to n fidi isele naa mule, agbenuso fawon olopaa ipinle Ogun, Abimbola Oyeyemi so pe iroyin naa ti te won lowo tipe, tawon si ti n so won. Sugbon nigba towo palaba won maa segi, se lawon tun gburo won lojo Wesde naa, tawon si ta awon olopaa SARS lolobo.

Yato si awon igbo ti won gba lowo won yii, awon olopaa tun gba tirela nla ti nomba idanimo e je KPP 339 XD, iyen tirela ti won ka Igbo naa mo lowo won.

Oyeyemi so pe nigba tawon eeyan naa n ka boroboro ni won jewoo pe onibaara won kan yo n je Uche lawon fe e lo ko won fun l'Eko.

O fi kun un pe Ahmed Iliyasu to je ogba won ti pase pe kawpn SARS si ko won pamo sogba won digba ti iwadii ipinle yoo fi pari. Bee lo so pe won gbodo loo mu Uche atawon to tun mo nipa ise buruku naa.


PÍN-IN KÁÀKIRI