Opo awon omo egbe oselu PDP nipinle Eko ti won gbo pe alaga egbe naa, Onarebu Moshood Adegoke Salvador ti i kede pe oun ti i fegbe naa sile darapo mo egbe oselu APC, loro naa si n se ni kayefi, ohun to si n jade lenu won ni pe opin ti de ba PDP patapata nipinle naa.
Bo tile je pe lati bii osu kan, loro naa ti n ja nile ti wahala ti wa ninu egbe naa, nitori bi won se ni Oloye Bode George to je okan lara awon agba egbe PDP ti ba nnkan je jinna ninu egbe naa ati bi won se loun atawon eeyan e kan se fee ran Salvador lewon apapandodo lori isele to waye ni Eti- Osa nibi ti won ti pa alaga PDP tijoba ibile Apapa.
Won ni pelu gbogbo bi won se ni Bode George n ba egbe je to, ti won si foro naa to awon oloye egbe lapapo lati gbe igbese lee lori, won ni won ko ri nnkan kan se sii, idi niyi ti Salvador atawon eeyan e fi pe ipade oniroyin lojo Aje, Monde, ana an ti won si so pe awon ti dagbere fegbe oselu PDP.
Ninu oro Salvador lojo naa lo ti so pe oun ti setan pelu awon omo eyin oun ti won to egberun meeedogun lati darapo mo APC. O so pe oun kabamo pe oun fegbe toun ti bere ise, amo ti won ko je ki oun pari e nitori awon asaaju ti won ko to asaaju se. O ni egbe naa kun fawon asaaju ti won ko le saseyori kankan.
Okunrin naa tun salaye pe ‘Alaga igbimo agba fegbe oselu PDP iyen BOT ati alaga egbe naa lapapo, Uche Secondus pe mi pe ki lo de ti mo fi fee fegbe naa sile, mo si salaye pe mo ti so fun won pe mi o le wa pelu Bode George ninu egbe mo. O lawon omo ipinle Eko ti won foruko sile je milionu mejo abo, won gbe ase egbe le Bode George ti iyawo e sise labe APC lowo, ti egbe ko wole ni woodu e ri lowo.’
‘Gbogbo igba lawon omo eyin okunrin yii ti da ipade wa ru ni Oregun atawon ibomii in, ti a ba si so fun won ni Abuja, won a so pe ka fi won sile, agba egbe ni won, nnkan si fojoojumo baje.Bakan naa ni oun atawon eeyan e, tun paro mo mi pe mo mo nipa isele to waye ni Eti- Osa, won lemi ni mo pase pe ki won da wahala sile, bi ki i ba se opelope Olorun ati pe agbofinro sise won gege bii ise, won ko so pe won ko ran mi lewon.
Okunrin yii wa so pe lojo Aje, Monde, to n bo yii loun atawon eeyan e bii egberun meeedogun yoo sayeye ni papa isere Agege niluu Eko pe awon ti domo egbe APC. Bee lawon eeyan e naa lawon ti i setan lati ba oga won loo sinu egbe tuntun naa. Ibeere tawon eeyan wa n beere ni pe bawon egberun meeedogun ba fi PDP sile, meloo ni yoo wa ku ninu egbe naa. Afaimo ko ma je pe PDP ti ku patapata nipinle Eko.
No comments:
Post a Comment