OWO OLOPAA IPINLE OGUN TE FULANI DARANDARAN MERIN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, August 22, 2018

OWO OLOPAA IPINLE OGUN TE FULANI DARANDARAN MERIN


Tani kii se pe awon olopaa SARS ipinle Ogun lo ogbon igbalode lati rowo to awon adigunjale kan ti won je Fulani, ti won so pe won ko nise meji ti won n se ju ki won maa fipa gba maalu, ki won si maa ji awon eeyan gbe beere owo lo.

Awon mejeeji
Gege ba a se gbo, won ni awon adigunjale yi ko ni ofiisi, bee ni won ko mo ara won soju daadaa, sugbon won ni bi won se n pade ara won, leyin ti won ti fi adehun sibi ti won ba ti fe e gbera loo sise ibi won.

Lojo Tusde, ojo kerinlelogun osu to koja nigba ti Ahmed Iliyasu to je Komisana olopaa ipinle Ogun n foju meta lara awon odaran naa towo te, iyen Audu Isa, omodun marundinlogbon (25), Yusuf Abdullahi omodun metadinlogoji (37) ati Ali Mohammed ti won loun wa losibitu nibi to ti n gba itoju pelu oku Abdullahi Nigar han fawon oniroyin ninu ogba oluleese won to wa ji Eleweran, Abeokuta lo ti so pe o ti pe tawon ti n dode awon odaran naa.

Nigba to n so bawon se ri won mu, oga awon SARS, Adams Ubah nigba to n b'AWIKONKO soro so pe o ti pe firoyin naa ti te won lowo, tawon si loo n duro sibi ti won n ko ibon si, bo tile je pe awon ko mo ibe, sugbon agbegbe naa lawon wa fun bii ose meta.

O lawon odaran naa so awon titi fun opolopo ojo, ti won si mo igba tawon ma n kuro nibe lati loo sinmi, o so pe laarin oogun iseju tawon fi maa n kuro nibe lawon odaran naa loo sare ko ibon won kuro, tawon ko si mo igba.

Ubah Adams so pe bi iroyin tun se kan si won lawon sese loo pade won nibi ti won ti n mura lati loo ji awon onisowo nla meji kan, Alaaji Shehu ati Alaaji Kabiru gbe, ki won si tun gba maalu won salo.

Nigba to n fi fidio ti won ya lati ibi ti won n ko ibon si ninu moto legbe ilekun ati ninu enjiini moto kasiri won ma baa tu sawon olopaa lowo han AWIKONKO, Ubah ni ara lo ru awon tawon fi bere sii beere ibi ti ibon won wa lowo won.

O so pe bawon se ri won ni won ti bere sii yinbon fawon, tawon naa si koju won, toro bi boolo o yago lona. Nigba yo n so bi won se pa Abdullahi Nigar, o loun gan an lo lewaju won, ati pe nigba to ri bi nnkan se n lo si, lo ju ibon owo e sile, to si loo fo mo SARS kan lorun lati gba ibon owo e.

Igba tawon SARS toku rii ninwon dabon boo daadaa titi to fi ku, nigba tawon si ye ara e wo, lawon ri gbekude orisirisi to so mo ara e.

Bo tile je pe ohun ta a koko gbo ni pe Boko Haram lawon ajinigbe odaran naa, sugbon Audu nigba to n soro so pe awon kii se Boko Haram sugbon awon kose mose nipa ijinigbe daadaa, ti ko si seni tawon ko le ji gbe beere owo lowo awon molebi won.

Audu so pe aimoye igba lawon ti ji eeyan gbe, tawon si ti gba milionu merin lowo enikan rii, kawon to o fi sile, ati pe eleekerin re e toun yoo ji eeyan gbe lasiri to o tu. O tun so pe maalu loun n da tele, ki won too pe oun sinu egbe ajinigbe, toun si ri pe owo wa nibe.

Nigba toun naa n soro, Yusuf to so pe omo bibi Kwara loun ni maalu ti won ba jibgbe loun maa n ra ta lagbegbe Obada-Oko, Abeokuta, sugbon lai pe yi ni won foju oun mo ona ajinigbe.

Yusuf ni tiẹ to ni ọmọ ijọba ibilẹ Asa, ni Kwara, loun, ṣalaye pe Ọbada-Oko, l’Abẹokuta, loun ti n ta maaluu tẹlẹ, oun maa n ra maaluu mi-in to jẹ wọn ji wọn gbe wa ni, oun yoo si ta a.

Nigba toun naa n soro, Ahmed Iliyasu so pe ojo kejila osu yi ni won ta won lolobo, toun si pase pe kawon SARS loo dena de won, sugbon tawon naa ko mu oro naa ni kekere fun won, sugbon towo pada te won.

Iliyasu ro awon araalu pe bi won ba kofiri eni to ni ogbe ota ibon lara, ki won ma se le eni naa danu, dipo bee, ki won tewo gba a, ki won si tete tawon olopaa lolobo.

Bee lo so pe oun ko tii setan lati gba awon odaran laye nipinle Ogun toun wa, nitori pe awon ko le koo gbe papo. Bakan naa lo so pe asiko re e fawon araalu, lati sun lorun asundokan.

Lara awon nnkan ti won gba lowo won ni ibon AK47 meje, pump action meji atawon ota ibon ti ko din ni ogbon.

PÍN-IN KÁÀKIRI