BABA AGBAAYA TO FUN OMO E LOYUN TI DERO EWON - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, August 22, 2018

BABA AGBAAYA TO FUN OMO E LOYUN TI DERO EWON

“Ise esu ni, ejo mi ko” loro ebe to n jade lenu bale ile eni odun marundinlaadota (45) kan, Ogbeni Julius Ochim ti won fesun kan pe o fun omo e tojo ori e ko ju odun mejidinlogun ta a foruko bo lasiri lo.


Julius
Gege ba a se gbo, kani omo naa mo tete loo foro naa to awon olopaa leti ni, o see se ki Julius ti ran an lo sorun apapandodo latari bi ko se faaye gba lati ni orekunrin, tabi ko maa jade bo se wuu.
AWIKONKO gbo pe lati odun 2009 tiyawo Juliu to je iya omo naa ti ku ni Julius ti n ko ibasun fun karakara, ti ko si gbiyanju lati fe iyawo min in, ko too di pe omo naa loyun mon on lowo ni nnkan bi odun meta aabo seyin.
Gbogbo bi won ni won se n beere lowo omo naa pe talo fun un loyun, ni ko jewo fenikeni latari bi won se so pe Julius ti dunkoko mon on pe se loun yoo pa a danu to ba fi le jewo, tiyen naa si se oro naa ni iso inu ekuu.
Leyin tomo e naa bimo tan fun un, ti won rii pe baba omo ko yoju, titi tomo naa fi pe odun meji aabo ni ko seni to fura sii pe Julius lo fun un loyun to fi bimo obinrin naa.
Ojoojumo la gbo pe Julius ta a ko tii mo ise to n se titi dasiko ta a sakojopo iroyin yi tan fi n ko ibasun fomo to bi ninu karakara, tiyen naa ko si reni to le so fun un lati gba a sile lowo odaju abiyamo baba e.
A gbo pe lati bii odun to koja ni omo naa ti n so fun baba e pe ko je koun maa lo sile oko, nitori toun ti ri eni toun fe e fe gege bi oko, sugbon se ni won so pe Julius fariga pe ko saaye fun lati lo sile oko.
Omo e ati omo-omo e
Gbogbo bi omo naa se n daamu Julius pe ko je koun maa lo sile oko, lo n so pe oun ko le fi sile lo fokunrin min in, igba to ya lo bere sii dunkoko mon on pe to bat un gbe oro so lenu, se loun yoo pa danu.
Ose meji seyin lomo naa gba tesan olopaa lo lati loo fejo baba e sun ni tesan olopaa to wa niluu Sagamu.
Bo tile je pe won ni Julius koko paro fawon olopaa nigba tasiri e tu, sugbon nigba to ya lo pada jewo, to si nbebe fun idariji pe ise esu ni. Julius nigba to n ro ejo e fawon olopaa so pe atigba tomo naa ti n tele okunrin min in jade loun ti bere sii nisoro pelu e ninu ile, ko too di pe o de tesan olopaa.
O ni kii se pe oun ko fe e fi omo naa sile lati loo fe okunrin min in, sugbon boun ba fi sile lo, ko ni sii aaaye foun mo lati maa ba a sun, idi niyii toun fi n dunkoko mon on.

Nigba to n jeri soro naa, agbenuso fawon olopaa ipinle Ogun so pe looto ni ati pe Komisana awon ti pase pe kawon si ti mole fungba tawon yoo tun fi ri okodoro oro daa daa, eyi ti yoo je gege bi eri fawon nile ejo, nitori pe lai pe lawon yoo foju e bale ejo.

PÍN-IN KÁÀKIRI