AWON AWORI LORILEEDE UK FE E GBALEJO OLOTA LOSU KEWAA ODUN YII - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, September 20, 2018

AWON AWORI LORILEEDE UK FE E GBALEJO OLOTA LOSU KEWAA ODUN YII

Gbogbo eto lo fi e e pari bayii fun ti ayeye igbalejo Olota tiluu Ota, Oba Adeyemi Abdukabir Obalanlege, (Lanlege EkunII, Arole Iganmode-Ogunfunminire) tawon eya Awori lorileede United Kingdom fe e se.


Lojo ketadinlogun osu kewaa to m bo yi la gbo pe ayeye igbalejo naa yoo waye nile itura Bexleyheath Marriott, South East, London.

Gege bi amugbalegbe Kabiyesi, Omoba Adeyemi Sulaiman Olusesi se fi to AWIKONKO leti laaro onii, o je ko di mi mo pe o ti pe tawon eya Awori naa ti n fe e gbalejo Oba Obalanlege, sugbon ti ko si aaye fun Kabiyesi, sugbon ni bayii, asiko naa ti wa a de.

Omoba Adeyemi Olusesi so pe ayeye naa yoo fawon omo bibi ile Awori kaakiri agbaye lanfaani lati tun foju-koju pelu Kabiyesi, ki won si ba Oba Olota tiluu Ota soro lori idagbasoke ati isokan ilu Awori, paapaa orileede Naijiria.

Bee lo tun so pe pelu bi Kabiyesi se n sagbateru ife, isokan ati idagbasoke kaakiri orileede Naijiria, paapaa awon adari ile Yoruba, lo mu kawon eya Awori yi naa pinu lati gba Kabiyesi lalejo, lati le mu ki isokan ati ife wo aarin awon Awori.

Bakan naa lo tun fi kun un pe abewo naa yoo tun mu idagbasoke ba eto oro aje ilu Awori, paapaa bawon to wa loke-okun yoo se ko eere oko dele.

Olota wa a lo anfaani naa lati ke si gbogbo omo ilu Awori jakejado pe ki won maa fi ife ba ara won lo, ki won si gba alaafia laaye, ki ipinu won nipa idagbasoke le wa si imuse.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI