E JAWO LORO SENETO ADELEKE O - BUHARI PARIWO SAWON OLOPAA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, September 19, 2018

E JAWO LORO SENETO ADELEKE O - BUHARI PARIWO SAWON OLOPAA

Aare orileede yii, Mohammed Buhari ti pase pe ki oga agba ileese olopaa jawo ninu oro esun ti won fi kan oludije fun ipo gomina ipinle Osun latinu egbe oselu PDP, Seneto Ademola Adeleke.


Ojo Satide to n bo yi ni idibo gomina yoo waye nipinle Osun, ti ipalemo si ti n lo lowo, sugbon lai pe yi ni ileese olopaa fi ikede sita pe ki Ademola Adeleke yoju si ileese naa lati wa so ohun to mo nipa esun sise magomago ninu idanwo NECO, iwa odaran ati igbimopo huwa buburu ti won fi kan oun atawon merin miin.

A gbo pe Seneto Ademola Adeleke ati aburo e kan ni won se mago-mago ninu idanwo NECO ti won se lodun 2009, atawon min in ti won fi kan won.

Gbogbo ona la gbo pe awon alatako Seneto Adeleke n gba lati rii pe ko roju-raaye ti idibo to n bo naa, ki won si le gba a mon on lowo.

Idi ni yii ti Aare Muhammadu Buhari fi pariwo sita pe ki ileese olopaa lorileede yi jawo ninu esun ti won fi kan seneto naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI