O MA SE O: IYAWO AMBODE KAN ABUKU LODO TINUBU - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, September 20, 2018

O MA SE O: IYAWO AMBODE KAN ABUKU LODO TINUBU

IGBAGBOYEMI ESUPOFO

Lati le wa ojutuu si wahala to de ba gomina ipinle Eko lori bi yoo se tun pada sejoba leekan si i, gbogbo akitiyan ti iyawo e, Bolanle Ambode naa tun sa laipe yii lo ja si pabo.


Ipinle Osun lohun-un ni oro ohun ti sele, o fe ma si omo egbe oselu APC ti ko si nibe lojo naa.

Aare orile-ede yii, Muhammed Buhari lo ko awon gomina atawon agbaagba egbe sodi lo si Osogbo nipinle Osun nibi ti won ti lo polongo ibo gomina fun Ogbeni Gboyega Isiaka.

Lara awon to si wa nibe lojo naa ni iyawo gomina ipinle Eko, Arabinrin Bolanle Ambode. Ki i se pe o lo polongo ibo bi awon yooku o, ohun kan pataki lobinrin yii lo se nibe lojo naa, Asiwaju Bola Tinubu gan-an lo wa lo.

Ohun ti a gbo ni pe latigba ti wahala bi oko e yoo se pada sile ijoba leekan si i se gbona mi-in yo lobinrin yii ti n wa bi yoo se ba Tinubu soro, sugbon ti kinni ohun soro pupo fun un.

Ni kete ti oro ipolongo ibo Osun si ti fe waye lobinrin yii naa ti pinnu wi pe oun yoo ba oko oun debe, ti oun yoo si so mo Tinubu lese, ki baba naa foriji awon, ki awon tun le lo sa kan si i.

Loooto lobinrin yii ba oko e de ipinle Osun, sugbon gbogbo akitiyan e lati ba asaaju egbe oselu APC yii soro, pabo lo ja si. Won ni bo ti se ri anfaani lati sunmo Bola Tinubu to fe ko alaye bole bayii, nise lokunrin naa kan rora ki i, to si rora rerin-in si i, tiyen si koju sibomi-in ni tie.

Gbogbo akitiyan iyawo Ambode lati ri ojuure Bola Tinubu lojo naa ni ko so eso rere, bee lo fi edun okan pada si Eko pelu oko e.

Te o ba gbagbe, lati nnkan bi ose meji seyin ni wahala ohun ti n fojoojumo bureke si i l’Ekoo lori bi gomina ipinle naa, Akinwunmi Ambode yoo se tun sejoba leekan si i.

Bi awon agbaagba egbe se tako o wi pe awon ko fe e mo, bee gege ni gbogbo awon alaga ijoba ibile to wa nipinle naa so pe, awon ko ni i tele e, ati pe okunrin kan toun naa ti ba Bola Tinubu ati Femi Pedro sise ri, iyen Babajide Sanwo-olu lawon n ba a lo.

Bi gbogbo jogodi yii se n lo, ohun kan ti Bola Tinubu, eni tawon eeyan tun mo si Ifa Eko, ti oro ba doro oselu si so ni pe, oun ko le so pe ki awon eeyan fi tipa tele enikan, ati pe eni ti egbe ba ti so pe awon fe loun naa n ba a lo.

Yato si eyi, ileese PSP to maa n kole ko idoti l’Ekoo ti Gomina Ambode gba ise lowo won to fi gbe e fun ileese mi-in naa ti jade bayii, won si ti so pe, bi awon osise ohun se po to l’Ekoo, bee lawon yoo se fi duro ti Babajide Sanwo-olu, nitori awon ko fe Ambode nipo ijoba Eko mo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI