AWON TO JA ONAREBU SIHOHO L'OSUN TI DERO OGBA EWON O - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, September 20, 2018

AWON TO JA ONAREBU SIHOHO L'OSUN TI DERO OGBA EWON O

SERUBAWON AYEGBAJEJE

Ile-ejo giga kan, to fikale siluu Osogbo, nipinle Osun, ti pase pe kiki won fi awon mejo kan ti won fesun kan pe won lu adari omo egbe to poju nile igbimo asofin ipinle Osun, Onarebu Timothy Owoeye ni jibiti owo tiye re je milionu mejidinlogorin pamo sogba ewon.


Awon odaran naa ni: Kazeem Agbabiaka, eni ogoji odun (40); Abdulrasheed Ojonla, eni odun marundinlaadota (45); Femi Oyebode, eni ogbon odun (30); Babatunde Oluajo, eni aadota odun (50); Adebiyi Kehinde, eni odun mejilelogoji (42); Oyebamiji Oyeniyi, eni odun mejilelogbon (32);/Ismaila Azeez, eni odun marundinlaaadota (45) ati Awodunmola Kehinde, eni odun merinlelogoji (44).

Be o ba gbagbe, lose to koja ni fidio kan jade sori ero ayelujara pe won mu Onarebu Owoeye nibi to ti n fi eje eeyan we lati setutu fun aseyori e nibi eto idibo to n lona nipinle Osun, iyen lojo Satide ose yii.


Lasiko to n gbe igbejo e kale, adajo kootu yii, Ogbeni Olusegun Ayilara, pase pe kawon olopaa loo fawon odaran afurasi yii pamo sogba ewon titi dojo kejidinlogbon (28), osu kesan-an, ti igbejo yoo tun bere ni pereu.

Ninu oro olopaa ijoba, ASP John Idoko lo ti salaye funle-ejo pe inu osu kerin ati osu keje lawon eeyan yii huwa ibaje yii ladugbo kan ti won n pe ni Oluajo, niluu Osogbo.


Olopaa yii te siwaju ninu oro e re pe, awon eeyan naa fogbon gba owo nla yii lowo Onarebu Owoeye lori pe awon yoo ba a setutu nitori iran iku ojiji ti won ri si i.

Sugbon nibi to ti n fe yii lawon ti won lawon fee ran lowo yii tun ti de awon eeyan kan si i lati waa mu un lasiko to n we iwe yii, ti won si gbe e sori ero ayelujara, to di pe awon eeyan bere sii fi seleya.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI