OPE O, IJOBA IPINLE OGUN TI GBA 17.3BILIONU OWO PARIS CLUB LATI FI SAN OWO OSU AJEELE AWON OSISE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, September 20, 2018

OPE O, IJOBA IPINLE OGUN TI GBA 17.3BILIONU OWO PARIS CLUB LATI FI SAN OWO OSU AJEELE AWON OSISE

Bi e se n ka iroyin yi, inu idunnu ati ayo ni awon osise, atawon osise-feyinti wa bayii, nigba ti ijoba ipinle Ogun ti Gomina Amosun n dari e kede sita pe ijoba apapo ti fun awon lowo yanturu, to je owo Paris Club Fund.


Owo naa ti ko din ni bilionu metadinlogun ati die (#17.3B) naira la gbo pe won yoo fi san owo osu ajeele awon osise, ati owo osu awon osise-feyintin.

Komisana foro eto isuna nipinle Ogun, Ogbeni Adewale Oshinowo lo kede sita losan onii lasiko to n bawon akoroyin soro nipa bi won se ri owo naa gba, ati nnkan ti won fe e fi owo naa se.

Oshinowo ni owo naa ni won yoo lo lati fi san owo ajeele awon osise-feyinti, owo alajeseku tijoba n yo, atawon owo min in to nii se pelu igbadun awon osise (Backlog of gratuity, Co-operative Deductiona, Severance, Furniture allowance of its workforce, social services).

O ni gomina ti pase pe ki won tete lo owo ti won ri gba ni ale ana, tii se Wesde fun awon nnkan toun ka sile yi, lati le mu awon ileri e se pe oun ko nii je osise yoowu lowo, toun ko si nii fawon eto won dun lasiko isejoba e.

Ninu oro ti e, Amofin Taiwo Adeoluwa to je akowe ipinle Ogun so pe ipinu yo wa yi ko seyin ife ti Gomina Amosun ni sawon osise e, atawon osise feyinti, ti ko si nii fe ki iya je won.

O tenumo on pe ore awon osise, paapaa araalu ni Gomina Amosun, nitori e lo se n wa gbogbo ona lati dun won ninu, ati pe igbese lati fi kun owo osu awon osise lati odun 2012, eyi to je ilopo meji owo osu ti won n gba.

Bakan naa lo tun fi kun oro e pe ijoba ipinle Ogun nikan lo n san owo osu to po ju lorileede Naijiria, eyi ti yoo mu ki awon osise tera mo ise won, ti yoo si tun sagbateru idagbasoke pupo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI