AYE O: MOTO TE OYINBO PA L'OGUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, September 25, 2018

AYE O: MOTO TE OYINBO PA L'OGUN

Ko seni to gbo nipa bi moto ayokele Kia Rio kan ti nomba idanimo e je KSF 725 AX se gba Oyinbo omo ile Syria kan danu lopopona Eko si Ibadan losan ojo Friade to koja yi ti aanu abiyamo ko nii se e.


Ohun ta a gbo ni pe ilu Akure nipinle Ondo ni Oyinbo naa ti won pe oruko e ni Ehisan Fahed, eni aadota odun ati amugbalegbe e ti n bo, ilu Eko lo si n lo pelu moto jiipu e, iyen Toyota Forerunner to ni nomba idanimo LND 345 CV.

Gege bi agbenuso ileese eso oju opopona nipinle.Ogun, Ogbeni Babatunde Akinbiyi se gidi e mule, o ni nitosi ileepo kan ti won pe ni Danco nisele naa ti waye ni nnkan bi aago meji koja ogun iseju.

A gbo pe moto kan loo kulo moto jiipu oyinbo naa, to si bo sile pe.koun ye e wo boya moto oun ko baje pupo, nigba to si rii pe.se.lo.kan ta ara e lasan ni, lo ba so fun amugbalegbe e naa pe.ko je kawon maa lo.

Nibi ti won ti yi oju pada pe.kawon wonu moto won ni won ni moto Kia Rio to.n sare asapajude bo ti gba won danu, lesekese ni ori Ehisan Fahed ti fo danu sile, ti ese amugbalegbe naa tun kan.

Awon to wa nitosi ni won sare fi moto le awako naa mu nigba to n salo, ta a si gbo pe won ti muu lo tesan olopaa to wa ni Sagamu, nibi ti won ti n yanju oro naa ta a fi sakojopo iroyin yi tan.

Mosuari Osibitu ti Olabisi Onabanjo, iyen OOUTH to wa leyin aafin Akarigbo tile Remo niluu Sagamu ni won gbe oku Ehisan ti won ni agbegbe Middle East lorileede Syria lo ti wa lo, ti won so gbe amugbalegbe e wo yara ti won ti n toju awon to nisele ijamba pajawiri lati toju e.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI