NITORI ATUNDI IBO: WON NI WAHALA NLA BE SILE LAARIN AREGBESOLA ATI OYETOLA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, September 25, 2018

NITORI ATUNDI IBO: WON NI WAHALA NLA BE SILE LAARIN AREGBESOLA ATI OYETOLA

...E ma da won lohun o, Iroyin eleje lasan ni - Oyetola pariwo sita

IGBAGBOYEMI ESUPOFO

Bo tile je pe ko si iroyin min in to tun n lo kaakiri ipinle Osun, paapaa orileede Naijiria lasiko yi, bi ko se ti idibo gomina to waye nipinle Osun lopin ose to koja yi, eyi ti ajo INEC sun siwaju di ojo Tosde to n bo yii.


Sibe, orisirisi awuyewuye ati aheso oro lo ti n lo kaakiri ipinle naa pe wahala nla be sile laarin Gomina Rauf Aregbesola ati adije sipo gomina nipinle naa labe egbe oselu APC, Gboyeya Oyetola latari bi won se lawon mejeeji ko fi oju gidi wo ara won.

Ohun ta a gbo ni pe Oyetola fi aidunnu e han si gomina Aregbesola pelu bi eto idibo naa se lo lopin ose to koja, ti won ni Aregbesola pelu awon to gbabodi fun okunrin naa.

Won ni bi eto idibo naa se lo si, to mu ki Oyetola padanu sowo akegbe e, iyen Adeleke bo tile je pe atundi ibo yoo si waye lawon ijoba ibile meta ko seyin Gomina Aregbesola.

Bee la tun gbo pe Oyetola so pe latigba ti egbe oselu APC ti fa oun kale gege bi adije ni ko ti dun mo Gomina naa ninu, ti ko si gba toun, to je pe kii da si nnkan toun ba n se.

Sugbon lai pe yi ni Gboyega Oyetola pariwo sita pe iroyin eleje lasan niroyin naa, ati pe awon to fe e ba toun je patapata ni won n gbe iroyin naa kaakiri, nitori pe ajosepo to dan monran lo wa laarin awon mejeeji, ti ko si si nnkan to le ya won.

Oyetola ni asiwaju rere ni Gomina Aregbesola je, to si je pe ise to se sile nipinle Osun ko le pare, ati pe itesiwaju ni ijoba naa yoo je boun ba fi wole gege bi gomina.

Bee lo gbawon araalu lamonran pe ki won ma se gba iroyin naa gbo rara nitori pe awon esu ti won wa nidi madaru ni won n sagbateru iroyin naa.

Bakan naa lo tun so pe oun ko ba ma ti soro nipa iroyin naa, sugbon nitori pe o see se ko je akoba nla fun atundi ibo to n bo lojo Tosde ose yii, lo je koun tete pariwo sita fawon araalu lati mo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI