Lojo Satide Abameta ose to koja ni Gomina ipinle Ogun, Ibikunle Amosun so o nita gbangba pe ojo Monde ana loun yoo fi oruko awon adije ogoji ti yoo dije lati egbe oselu APC sita, iyen awon adije tegbe naa fa kale, ti won pe ni Consensus candidates.
Bo tile je pe kii se gbogbo eeyan, paapaa awon omo egbe naa lo fara mo, to.mu ki won maa so pe Gomina Amosun lo n pase egbe naa, tawon kan si so pe iro ni, awon ti kii se ojulowo omo egbe naa lo fe e da wahala sile.
Sugbon se loro naa yi pada lojo Monde ana nigba ti egbe oselu APC pe gbogbo awon omo egbe naa lati wa a sepade, ki won si yan eni ti won ba fe e, nitori pe ofin egbe naa ti laa kale pe ki egbe fa enikan soso kale, ti gbogbo won si faramo.
Ipade naa waye ni gbagede Presidential Lodge to wa ninu Ibara, Abeokuta.
Nibe ni Gomina Amosun ti ni ki gbogbo awon adije sile igbimo asofin ipinle Ogun jade sita, ki gbogbo won ba ara won soro, ki won si pa enu po lati yan eni kan soso laarin won.
Bawon kan se n fapa jari, bee lawon kan n so pe igbese ti Gomina Amosun gbe yi je eyi to tona, to si fi apere rere lele gege bi adari gidi.
Leyin o reyin la gbo pe metalelogun (23) ninu merindinlogbon (26) lawon adije sipo naa ti won pa enu po fa kale, iyen ti a mo si consensus candidates, awon la gbo pe won je ojulowo awon ti yoo gba tikeeti lati dije fun ipo naa lodun 2019.
Igbesi yi, titi di bi e ti n ka iroyin yi lowo lo mu kawon eeyan to gbo nipa ohun ti Gomina Amosun se yi maa kan saara sii, ti won si n gbe osuba kare fun un, pelu awon adari egbe oselu APC.
Nigba to n soro, Komisana foro iroyin, Onarebu Dayo Adeneye so pe gbogbo igbese ti Gomina Amosun gbe yi, lati fi yanju wahala to see se ko sele nigba ti eto idibo ba de ni, nitori pe gbogbo awon adije funra won ni won fa enikan soso ti won finutan kale pe ko loo soju won nile igbimo asofin.
Adeneye so pe isakoso Gomina Amosun je eyi ti kii fi igbakan bo okan ninu ni, to si ye ki awon egbe oselu to ku mulo.
O wa a gboriyin fun Gomina Amosun pelu awon adari egbe oselu APC fun bi won se fowosowopo lati gbe iru eto bayii kale.
Gomina Amosun funra e seleri pe eto naa si n te siwaju lonii ojo Isegun, Tusde, nibe ni won yoo tun ti yan awon adije to n lo siluu Abuja.
No comments:
Post a Comment