Won Ni Femi Otedola Fee Di Gomina Eko - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, September 12, 2018

Won Ni Femi Otedola Fee Di Gomina Eko

Bi iroyin to te AWIKONKO lowo laipe yi ba fi le je otito, a je pe ko seni ti ipo gomina ko wun lati de, eyi gan lo lo nibamu pelu bi won se so pe gbajugbaja onisowo nni, Femi Otedola ti so pe oun gba lati jade dupo gomina ipinle Eko labe egbe oselu PDP lodun 2019.


AWIKONKO gbo pe o ti se die ti egbe oselu PDP ti n ba gbajumo onisowo naa soro pe kawon fun un ni tikeeti gomina egbe naa, ko le je eni ti won yoo fa kale fun ipo gomina lodun 2019.

Sugbon lai pe, iyen ojo Tusde ana la gbo pe okunrin naa gba lati ba egbe oselu PDP se, paapaa to tun so pe oun ti setan lati jade du ipo naa.

Gbajumo oniroyin nni, to tun je oludasile iwe iroyin Ovasion ati The Boss, Oloye Dele Momodu lo je ki oro naa di mi mo nigba to ko o sori ero ayelujara pe gbogbo nnkan ti n pada bo sipo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI