Ẹru Amosun ba Ọbadara lo ba loun ko dije fun ipo sẹnetọ mọnipinlẹ Ogun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, September 11, 2018

Ẹru Amosun ba Ọbadara lo ba loun ko dije fun ipo sẹnetọ mọnipinlẹ Ogun

Bunmi Adeoti

L’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ to koja yi ni Gomina Ibikunle Amosun sọ nita gbangba nibi ipade awọn ọmọ ẹgbẹ APC tipinlẹ Ogun pe ki gbogbo awọn to n tẹnu bọlẹ kaakiri lọọ gbẹnu dakẹ nitori oun ti i jade bayii lati dije fun ipo sẹnetọ fun Ogun Central.


Bo si ti sọ ọ tan an lawọn ọmọ lẹyin ẹ ti wọn wa nibẹ ti n fo soke, bi ẹni ti ko gbọ iru ẹ rii pe Amosun fẹẹ pada si ẹsẹ aarẹ ẹ, iyẹn sẹnẹto to ti wa tẹlẹ, ni wọn ba n ki ara wọn ku oriire. Ṣugbọn ko to digba naa ni Sẹnẹto Ọbadara naa ti fi erongba ẹ han lati jade dupo naa lẹẹkeji labẹ ẹgbẹ oṣelu APC.

A fi bo ṣe di aarọ ọjọ Ẹti, Furaide, ti Sẹnetọ Ọbadara gbe atẹjade kan sita pe niwọngba ti Gomina Amosun ti sọ ipinnu ẹ pe oun fẹẹ dije dupo, oun fipo naa silẹ fun un. Awọn eeyan ko kọkọ gbagbọ tẹlẹ pe Ọbadara to ti n leri pe oun ni yoo di sẹnetọ lọdun 2019, ni ko tiẹ janpata to fi fipo naa silẹ.

Awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu naa ti wọn gbọ bi ọkunrin naa ṣe sọ pe oun ko dupo mọ, ẹru Amosun lo n ba a ati pe ko fẹẹ fowo ẹ jona ni. Wọn ni bi ko ba juwọ silẹ, ti Amosun ko dije, wọn ko lee fun ni tikẹti tẹlẹ, nitori ko si ni kankọọsi Amosun tẹlẹ.

Bo tilẹ jẹ pe ọkunrin naa sa ipa fawọn iṣẹ akanṣe to ṣe lawọn aarin gungun ipinlẹ Ogun, eyi ti wọn ni ẹni to wa nibẹ lakooko yii ko ṣe ida ogun ẹ, amo oṣelu to wa nipinlẹ Ogun ko ri bẹẹ, wọn ni ka ni Ọbadara ni igboya ni, ko yẹ ko tete gbe igbesẹ to gbe yẹn. Idi niyii ti wọn fi ni ẹru Amosun lo n ba a to fi tete juwọ silẹ 

Awọn kan tun sọ pe oun to mu ki Ọbadara tete gbe igbeṣẹ naa ni ki Amosun ma ba a lo agbara ipo to wa lori redio to da silẹ iyẹn Sweet Fm.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI