MO FE E MU OLAJU WO OSELU IPINLE OGUN - ADEMUYIWA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, September 7, 2018

MO FE E MU OLAJU WO OSELU IPINLE OGUN - ADEMUYIWA

Lojo Fraide to koja yi ni Onarebu Adeyemi Ademiyiwa lo si ofiisi egbe oselu APC nijoba ibile Abeokuta South lati loo fi erongba e lati jade dupo omo ile igbimo asoju-sofin ipinle Ogun han fawon Oloye egbe naa.


Onarebu Adeyemi Ademuyiwa ti alaga woodu e, iyen Woodu kesan an to wa ni Ijeun-Titun, Onarebu Olajide Olayinka lewaju e loo la gbo pe o ti figba kan ri gbe apoti ipo naa, sugbon kadara ko je ko wole.

Nigba to n soro nibi eto naa ni Okejigbo niluu Abeokuta, Adeyemi so pe ipinu rere toun ni fun awon eeyan oun lo je koun tun fe e pada lo, toun si nigbagbo pe Olorun yoo gbe oun bori awon tawon jo fe e figagbaga.


Nigba to n gba omo bibi Oke-Bode niluu Abeokuta naa lamonran, alaga egbe oselu naa nijoba ibile Abeokuta South, Onarebu Lateef Adenekan so pe bo tile je pe kii se eeyan tuntun sawon, tawon si mo ipa ribiribi to ti ko ninu egbe naa, sibe, o ni lati mura daadaa, kii ipo naa le ka mon on lowo.

Lara awon to wa nibe ni; Onarebu Tunji Fagbenro to je alaga egbe naa ni Constituency II atawon amugbalegbe e.

Ileewe alakobere Surulere Baptist lo ti bere eko e, Apostolic Church Grammar School lo tun ti tesiwaju, ko too lo si fasiti kan ni UK nibi to ti ko eko nipa bi a se n the iwe, iyen Printing Management, bee lo tun ko eko nipa Computer Science ni Amerika.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI