Awon eeyan ilu Atan, Ado-Odo, Agbara ati Ikoga ti ke gbajare sijoba ipinle Ogun pe ko gba awon lori oju ona to gba ilu meteeta yii koja se n fojoojumo femi-in awon eeyan sofo, tokan awon ko si bale lori e mo.
Won ni ipo ti oju ona wa yii buru jai, opo igba si ni ijamba oko ti paayan soju ona yii, eyi to n ba awon ninu je pupo.

Yato eyi, won tun so pe bi koto giriwo se wa lojuona ohun n sakoba fun eto oro aje adugbo yii, nitori pe ko seni ti yoo gbe ileese e wa sibe pelu ipo ibanuje toju ona naa wa, bee lo n di lilo ati bibo oko atawon eeyan lowo.
Won waa rawo ebe si gomina Ibikunle Amosun pe ko tete bawon wa nnkan se soju ona naa, nitori pe inira ati wahala nla lo n mu bawon ni gbogbo igba.
Lati: OJUTOLE-TOKO