IDI TI MO FI FE E YA WERE - OKUNNU SORO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, September 18, 2018

IDI TI MO FI FE E YA WERE - OKUNNU SORO

ABIMBOLA ABERUAGBA

Gbajumo osere tiata, to tun je aderin posonu nni, Wale Akorede topo awon eeyan mo si Okunnu soro, ile kun, o loun ko le gbagbe ojo toun fe e ya were, to si maa n je nnkan toun ko le gbagbe lailai.


Okunnu lo soro naa lai pe yi nigba to n dahun ibeere, paapaa nipa awon ojo ti ko le gbagbe latigba to ti wa nidi ise tiata to yan laayo naa.

Akorede, eni aadota odun naa so pe odun 1984 lodun toun ko le gbagbe nigbesi aye oun, nitori kayeefi nla lo.sele lojo naa, ko da a, to ku die koun ya were, sugbon ti Olorun gbakoso.

Gbajumo osere alawada naa ni lojo yen, awon sese pari yiya sinima ni, nigba tawon si setan ni won ba foun lowo, ogota kobo (60kobo), paapaa bo tun se je pe igba akoko toun yoo gba owo nidi ise naa ni yen, die lo ku to loun fe e ya were, nitori pe bii igba ti won foun ni ogota milionu lo ri.

Ninu oro e, o so pe "Igba akoko ti mo gba owo ise ti mo se, iyen lodun 1984, ti won fun mi ni ogota kobo. Nigba ti mo gba owo naa, ti mo ye e wo o, die lo ku ki n ya were. Inu mi dun koja afenuso, o tun fun mi ni koriya lati tera mo ise tiata gidi gan. Sibe, lowolowo yi naa, mo si n gba owo gidi lori awon ise ti mo n se."


Bakan naa nigba to n soro nipa bo se je pe ipa alawada lo n ko ju ninu sinima, o ni kii se bee, ati pe ko si ipa toun ko le ko, sugbon boun ba ko ipa ti ko nii se pelu awada, opo awon eeyan ni won si n ri oun gege bi alawada.

Bee lo tun so pe "Inu mi maa n dun ni gbogbo igba ni, mi o je ki adojuko aye yi ko irewesi okan ba mi. Lati kekere ni mo ti feran ise tiata, bo tile je pe awon obi mi ko fara mon on. Leyin iku baba mi ni mo sese wa a fara mi jin in daadaa sidi ise tiata.

"Opolopo igba ni mo ti salo kuro nile nitori pe mo fe e kopa ninu awon ise kan. Igba to di pe iya mi naa n ri mi lori ero amohunmaworan, iyen telifisan ni iya mi sese tewo gba mi, to si duro ti mi.

"Ise karakata ni mo n se daadaa tele, sugbon ise tiata n ja ninu isan ara mi. Bii papa osere ni ise okoowo ri, ko si tii si ise aje ti mo le se to maa da bi ise yii. Ayanmo mi ni ise tiata je.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI