KAYEEFI: OLOPAA GUN OKO RE PA L'EKO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, September 18, 2018

KAYEEFI: OLOPAA GUN OKO RE PA L'EKO

AYEFELE OKEOWO

Olopaa kan toruko e n je Folake Ogunbodede, to n sise ni tesan olopaa Ipaja, niluu Eko lawon agbofinro n wa bayii lori esun pe o gun oko e, Taiwo lobe, nitori ede aiyede to sele laarin won.


Gege bi Ojutole se gbo, aaro ojo Abameta, Satide to koja ni ija  kekere kan sele laarin won, ti Taiwo si fi ile sile funyawo e olopaa ti won pe ni sajenti yii.

https://mpulse.mtnonline.com/#utm_source=awikonko&utm_medium=banner&utm_campaign=mpulse


Nitori bi Taiwo se sa kuro nile fun iyawo e yii lo se so fun un pe oun ko gbodo ri i ko pada wa sile mo, sugbon ale ojo naa lokunrin ti won gun lobe yii pada wa sile, pelu erongba pe inu iyawo oun yoo ti ro, sugbon ohun ti ko ro lokan lo ba pade, nibi to to jokoo si lobinrin olopaa yii ti gun un lobe, ti Taiwo si subu lule.

Bi Folake se ri i pe oun ti daran lo sa lo, awon ara adugbo ni won gbe Taiwo lo sile iwosan nibi to ti n gbatoju lowo bayii. 

PÍN-IN KÁÀKIRI