IJOBA AMOSUN TI SU ARAALU, ADP NI YOO GBA WON SILE - EGUNLETI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, September 6, 2018

IJOBA AMOSUN TI SU ARAALU, ADP NI YOO GBA WON SILE - EGUNLETI

...Ẹgbẹ ADP ni yoo jawe olubori nipinlẹ Ogun lọdun to n bọ - Wale Egunleti

Bi wọn ba sọ pe ẹgbẹ oṣelu wo lo tun n rinlẹ kaakiri ipinle Ogun bayii, ti wọn tun ti wa ni imurasilẹ fun idibo tọdun to n bọ nipinlẹ Ogun, Won ko ni tii darukọ ki wọn to sọ pe ẹgbẹ oṣelu, Action Democratic Congress, iyen ADP ni.  Bo tilẹ jẹ pe ko tii  ju ọdun kan lọ, ti wọn da ẹgbẹ naa silẹ,  sibẹ ṣe lo n figagbaga pẹlu awọn ti wọn ti wa nibẹ tẹlẹ lo. Idi niyii tawọn kan fi sọ pe bii nnkan ṣe n lọọ yii, o ṣe e ṣe ko jẹ pe ẹgbẹ naa ni yoo rọwọ mu ninu eto idibo odun 2019 to n bo lona.

Laipẹ yii ni alaga ẹgbẹ naa, Oloye Adewale Egunleti ṣe ifọrọwerọ pelu oniroyin wa nipa bi wọn ṣe da ẹgbẹ naa silẹ, ibi ti wọn ba a de ati imurasilẹ wọn fun ibo gomina atawọn ipo yooku, ti yoo waye lọdun 2019. Ohun ti alaga naa ba wa sọ ree:

Ohun to mu wa da ẹgbẹ naa silẹ.

Ẹ ṣe pupo, loootọ bi a ba ni ka woo yoo ti le ni ọdun kan ta a da ẹgbẹ ADP silẹ, ohun ta a le sọ pe o mu ki a da ẹgbẹ naa silẹ ko jinna rara, bi ẹyin oniroyin naa ba woo, ilu le, ko fararọ, inu awọn eeyan ko dun, iya n jẹ wọn, awọn to si wa nidi agbara, o dabi pe emi o gba tiẹ, iwọ ko gba temi ni wọn n ba kaakiri.

Owo Naijiria ni gbogbo wọn n le kaakiri, wọn ti gbagbe pe wọn dibo fun wọn ki wọn lọọ sibẹ lati ṣoju araalu lati mọ bi nnkan yoo ṣe dara fawọn mẹkunnu, nigba tawa bẹrẹ si ni i wo, aa ri i pe awọn eeyan n pariwo pe inu inira lawọn wa yii, ti ko si ifọkanbalẹ kankan fawọn, idi niyi tawọn eeyan kan fi jokoo fun idasilẹ ẹgbẹ tuntun.

Bi ẹ ba lọọ wo iwe ofin ẹgbẹ wa, ẹ o ri i pe o yatọ si eyi ti wọn ti n ba a bọ tẹlẹ, idi niyi ti wọn fi sọ pe awọn le jẹ ọmọ ẹgbẹ naa tẹlẹ o ṣugbọn ki awọn wa ẹgbẹ mi in ti yoo gba awọn mẹkunnu silẹ lọwọ inira tawọn jẹgudujẹra oloṣelu n ko wọn si i.

Awọn ti le bawọn wa ninu ẹgbẹ naa ri tẹlẹ ṣugbọn awọn gbọdọ wa ọna mi in ti yoo gba yatọ si tẹlẹ, nitori gbogbo ibi ti wọn ba iṣẹ ibajẹ yii ti to gẹ. Eyi lo si faa ti wọn fi n bawọn eeyan sọrọ, bo tilẹ jẹ pe yoo ṣoro fun wọn lati gba wọn gbọ.

Ọpọ wọn lo n sọrọ nipa awọn ọdọ, awọn abarapa atawọn omode,ipo ti wọn wa ko tẹ wa lọrun, ọpọ wọn ni ko niṣẹ. A o ri i pe wọn fiya jẹ wọn ju, to ba jẹ ileewe ijọba dara ni, awọn araalu ko nii maa mu ọmọ wọn lọ sileewe aladaani, to ba si maa wa, awọn olowo gidi ni wọn yoo maa lọ. Wọn ti ba eto ẹkọ jẹ patapata. Idasilẹ ẹgbẹ wa wa fun yiyi igba pada fawọn araalu.

Ẹgbẹ to darapọ mọ ADP ki i ṣe PDP nikan

Emi naa gbọ pe wọn ni awọn to kuro ninu ẹgbẹ oṣelu PDP lo wa ni ADP, irọ to jinna si ootọ ni, mo fẹ kẹ ẹ mọ pe ẹni to jẹ alaga ẹgbẹ naa lapapọ niluu Abuja, iyẹn Alaaji Yabag Yusuf Sani, emi ko gburo ẹ ri ninu oṣelu, loootọ ni wọn pe awọn bii Baba wa, Alani Bankọle ti wọn jẹ alaga igbimọ agba fẹgbẹ naa.

Baba Bankole yii pẹlu awọn to kọ iwe ofin fẹgbẹ oṣelu PDP, o si tun pẹlu awọn to kọ APP laye ọjọun. Awọn eeyan to wa ninu wa nibi, awọn ara igberiko ni wọn, ko si agbowo rin ninu wa, ohun tawa n sọ fun wọn ni pe a fẹ ki wọn ṣejọba ara wọn, bi wọn ba yan kanselọ, o gbọdọ jẹ ẹni ti yoo maa mọ nnkan to lọọ ni wọọdu ẹ, bẹẹ gẹlẹ awọn oye oṣelu yooku. Ọrọ owo yii naa ni iṣoro wọn, epo yii naa si ni. Ko sẹni to n wẹyin wo mọ ninu wọn ti wọn ba depo naa tan.

Gbogbo awọn nnkan wọnyii la a gbọdọ fopin si, awa kan la a si ni lati bẹrẹ ẹ. Ẹni kan lo sọ fun wa pe ẹnu ẹyin oloṣelu dun, mo ni bẹẹni, ṣugbọn beeyan ko ba a ra irọ ko le ri ootọ ra.

Ki i ṣe nitori Alani Bankọle la ṣe da ẹgbẹ ADP silẹ

Awọn kan maa n sọ pe nitori Baba Alani Bankọle la ṣe da ẹgbẹ ADP silẹ tabi pe awọn lo ni, ọrọ ko ri bẹẹ, mo sọ tẹlẹ pe awọn kan wa to jẹ pe iṣubu ẹgbẹ ni wọn yoo maa wa, ki lo buru ju bi Baba Bankọle ba n ṣe ẹgbẹ kan, tọmọ rẹ naa n ṣe.

Ṣe gbogbo awọn to wa ninu ẹgbẹ wa, ṣe ẹbi Bankọle ni wọn, to ba tiẹ jẹ pe ẹgbẹ wọn ni, ṣe awọn lo maa ṣe gomina, lo maa ṣe sẹnetọ, lo maa ṣe ọnarebu, ṣe awọn naa ni, emi o ro pe o yẹ kawọn eeyan maa sọ nnkan ti ko nitumọ.

Ati pe ẹgbẹ yii ki i ṣe tipinlẹ Ogun nikan, gbogbo ipinlẹ lo wa, bi ẹnikan ba wa n ṣe daadaa, awa le maa fẹran rẹ, tabi ri oju ẹ, ero wọn ni pe awọn ko nii jẹ kiru onitọhun gbe apoti, to ba si gbe apoti, ti ẹgbẹ ba ro pe oun lo le yanju iṣoro to wa nilẹ, awọn ko nii fun un ṣe wọn ti gbagbe pe Ọlọrun ju ẹda lọ.  

Bo tiẹ jẹ pe awọn lo daa silẹ gẹgẹ bi wọn ṣe sọ, ko si nnkan to buru nibẹ. Eyi to jẹ awa logun ni pe ṣe awọn to fẹẹ dije yii, ṣe ki i ṣe awọn ti yoo tun dakun iṣoro wa, a n fẹ iyipada to muna doko, ki i ṣe iyipada si laburu, ọrọ pe Bankọle lo da ẹgbẹ silẹ kọ lo kan wa bayii.

Ilara ni Amosun fi le wa kuro ni sẹkiteriati ta a wa tẹlẹ

Lojiji lawa naa gbọ pe Amosun atawọn eeyan ẹ ni ki wọn wo sẹkiteriati ta n lo gẹgẹ bi ọfiisi to wa ninu Ibara Housing, awa ko mọ nnkan to ṣẹlẹ. Ki awa naa to gba ọfiisi to wo naa, a kọkọ woo yika pe awọn ọfiisi to wa lagbegbe, a ri i pe eyi to bojumu tawọn ileeṣe nlanla naa wa nibẹ to si ba ode oni mu, iyẹn la wa ro, ta a fi ni kawa naa maa lo sibẹ.

Latigba ta a ti de bẹ, jẹjẹ wa la a n lọ, a ko lọ ba eeyan ja, bẹẹ la ko da wahala silẹ, a fi bi wọn ṣe de ti wọn sọ pe ibẹ ko bofinmu, awa ko si fẹẹ fa wahala, nitori ẹ la ṣe wa ibo mi in laimọ pe Ọlọrun ti fọrọ naa ṣe ile ọba to jo, ẹwa lo bu sii.

Nnkan tawa ri ninu ọrọ naa ni pe wọn fẹẹ maa fin wa lọran ni, ati pe wọn n jowu wa, wọn ti ri ọwọ tawọn eeyan ba wọnu ẹgbẹ naa,  gbogbo ẹ lo n jawọn laya, o ti di nnkan ti wọn ko lero, idi niyi ti wọn fi ti ilara bọ.

Awa ko ri ti egbe ADC Obasanjo ro nipinlẹ Ogun

Loju tiwa, awa ko ri ẹgbẹ ADC, Ọbasanjọ ro gẹgẹ bii alatako, nitori nnkan ti Baba sọ ni pe tawọn ba ti da ẹgbẹ silẹ tan, awọn a yọwọ nibẹ. Awa wa nibi ta a n ṣisẹ wa lọ, nnkan temi kan ri ni pe ADC  ati ADP ti fẹẹ jọ ara wọn, awọn mi in ti fẹẹ maa gbe fun ara wọn, awa o si fẹẹ ba ẹnikẹni ro ẹjọ.

Awa ṣetan lati ṣiṣẹ pọ pẹlu ẹgbẹ oṣelu mi in

Bẹẹni, a ṣetan, iyẹn ẹgbẹ oṣelu ti ajọṣe wa fun araalu yoo dọgba.Ti ki i ṣe pe wọn kan fẹẹ maa kowo sinu ẹgbẹ, a fẹẹ jokoo ka wo nnkan to n dun awọn eeyan lọkan, nnkan ti wọn n fẹ, ki ara le tu awọn araalu, ohun ta da ẹgbẹ yii silẹ fun niyẹn.

Ijoba Amosun loju temi

Loju temi o, ko sẹni to wa sibẹ lati wa ba ilu jẹ.Nnkan tijọba ba lagbara lati maa ṣe, ko maa ṣe e. Ṣọja lọ, ṣọja bọ nijọba, bi ẹnikan ba de yoo ṣe iwọn to le ṣe, ṣugbọn mo nigbagbọ pe fun ilọsiwaju ipinlẹ ati orileede, o yẹ ki ipade laarin araalu ati ijọba maa waye loorekoore.

Nnkan kan ti mo mọ to si n jẹ ẹdun ọkan fun mi ni pe o yẹ ki a maa woye pe bawo la ṣe fẹẹ jẹ ki ipinlẹ ati orileede ri laarin ogun ọdun. O yẹ ki wọn ni eto pataki bawọn nnkan yoo ṣe ri fọjọ iwaju, ti ijọba kan ba tiẹ de ti ko pari ẹ, ijọba to ba wọle lẹyin ẹ yoo tẹsiwaju nibi to ba a de. Awa sin awọn araalu ni ki i ṣe pe ki ẹnikan de bẹ, ko maa ṣe nnkan to wuu.

Aye wa fun Kashamu lati darapo mọ wa

Ko si nnkan to buru ti Buruji Kashamu ba sọ pe ẹgbẹ wa wu oun lati darapọ, ko maa bọ, a maa fi tayọ gba a koda ẹnikẹni to ba wuu ni ore ọfẹ wa fun un lati darapọ mọ wa ṣugbọn sa, o gbọdọ tẹle ilana ati ofin ta a fi da ẹgbẹ yii silẹ. To ba ti faramọ nnkan ti iwe ofin ati ilana ADP sọ, iyooku kere.

Bakan naa, to ba ti moju kuro ninu gbogbo ratirati ti wọn n ba bọ tẹlẹ ninu ẹgbẹ ti wọn wa tẹlẹ, aa ṣetan lati ba a ṣiṣẹ papọ, niwọngba to jẹ pe ẹgbẹ oṣelu Naijiria ni.Lara ẹ ni pe ti wọn ba fun un ni tikẹti to wọle, o gbọdọ wa maa yẹ awọn eeyan ẹ to n ṣoju wo, o si gbọdọ mọ pe ko nii maa foju ẹgbẹ ri rẹdẹrẹdẹ tabi koun naa maa ṣowo ilu baṣubaṣu.

Eto abo mẹhẹ lorileede yii

Bi a ba ni ka sọ tododo, eto abo mẹhẹ ni orileede wa, Ọlọrun nikan ni ko saanu wa. Aarẹ wa ni ki a bẹ, ki wọn foju rere wo awọn mẹkunnu, ki wọn wa ojutu si bawọn Fulani darandaran ṣe n pa awọn eeyan bii ẹni pa ẹran, bẹẹ ni ki wọn tun ṣiṣẹ lori awọn ajinnigbe.  Inu Ọlọrun ko dun si ki a maa pa eeyan.

ADP ko ṣiṣẹ fun Dimeji Bankole lati di gomina o

Isọkusọ lawọn to n sọ pe nitori ki Dimeji Bankọle le di gomina ni ẹgbẹ ADP ṣe n ṣiṣẹ ta a n ṣe yii, ko si ootọ nibẹ, awa ati Dimeji ti jọ wa papọ, o ti le ni ọdun marun un, ti a jọ n ṣiṣẹ lọ, a jọ wa ninu ẹgbẹ yii naa ni, nnkan to dara ni lati maa ba eeyan rere rin.Ki i ṣe ẹni ti ko ni nnkan ṣe gbogbo wa jọ n ṣiṣẹ papọ, ẹnikẹni to ba wuu ninu ẹgbẹ lo le dije fun ipo gomina, gbogbo iyooku ti wọn n sọ yẹn, aheso lasan ni.

Awa o pin ipo gomina si ẹya kankan

Iwe ofin wa nipinlẹ Ogun ati ti ẹgbẹ wa ko ti i sọ pe wọn ti n pin ipo gomina ni ẹya kan si omi in, ohun tawa duro lori ni pe ibikibi lẹni to ba nifẹẹ lati jade, ti le jade wa, lẹyin naa la maa ṣe pamari, ohun ni yoo sọ ẹni ti yoo ṣoju wa. Bi awọn ọmọ ẹgbẹ ba bilifu ẹni ti wọn roo pe o le ṣe nnkan ti wọn n fẹẹ ti ko si nii doju ti wọn, oun ni wọn yoo dibo fun un. Emi ro pe nnkan to dara niyẹn, ki i ṣe pe boya Ẹgba, Yewa tabi Ijẹbu lo gbọdọ ṣoju wa. Gbogbo wa lo tọ si.

A ti bẹrẹ irinajo kaakiri ipinlẹ Ogun

Lọsẹ to kọja lọhun la a ti bẹrẹ irinajo sawọn ijọba ibilẹ ogun (20) to wa nipinlẹ wa, idi ta fi n ṣe bẹẹ ni lati bawọn ọmọ ẹgbẹ wa sọrọ, a tun fẹẹ mọ ibi ti nnkan de ati lati gbaradi fun ibo to n bọ lọdun 2019.

PÍN-IN KÁÀKIRI