IPINU TI MO NI YATO SI T'AWON ASIWAJU NIDII OSELU - Shomide - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, September 19, 2018

IPINU TI MO NI YATO SI T'AWON ASIWAJU NIDII OSELU - Shomide

Okan lara awon oludije sipo omo ile igbimo asoju-sofin kekere niluu Abuja, House of Reps lodun 2019, Ogbeni Ayodeji Michael Shomide ti je ko di mi mo pe ipinu rere ati idagbasoke alailegbe toun ni fawon ara agbegbe oun yato si tawon asiwaju ti won ti se tele atawon to n se lowo, lo je koun fe e lo soju won niluu Abuja ninu idibo to n bo lona..

Shomide to je omo bibi Ago-Oba niluu Abeokuta soro naa lai pe yi, iyen lose to koja lasiko to n b'AWIKONKO soro nile egbe oselu APC to wa ni Abeokuta South, iyen Okejigbo, Abeokuta, lasiko to loo farahan awon oloye egbe naa ti Alaaji Lateef Adenekan je alaga fun.

Gbajumo onisowo naa so pe bo tile je pe asiko ipolongo idibo ko tii de, sibe oun ko gbodo salai ma tete wa a farahan fawon oloye egbe toun fe e gba jade. Bee lo seleri pe oun setan lati fowosowopo pelu won, koun si maa tele amoran ati ase ti won ba pa foun.

Bakan naa lo tun je ko di mi mo pe igba akoko re e toun yoo wonu oselu, toun si mo pe pelu awon iriri toun ni lorileede Naijiria ati loke okun toun ti kawe yoo je koun se daadaa, paapaa bo se je pe asiko awon odo lati gbajoba la wa yii.

O wa a fi kun un idi ti ko tii se si idagbasoke daadaa ni bi awon olidibo ko tii se yan olooto bii toun sipo, toun si mo pe oun ko nii dale won.

Nigba to n soro, alaga ijoba ibile naa, Alaaji Lateef Adenekan so pe bo tile awon nigbagbo ninu Shomide nitori tawon mo on daadaa, sibe oun ko le salai ma gba nimonran pe ko mura daadaa, nitori tawon to fe e jade dupo naa si n bo, paapaa tawon min in ti wa a ba won lori ipo kan soso naa.

PÍN-IN KÁÀKIRI