KO TII TO ASIKO FUN ODO LATI DI AARE ORILEEDE NAIJIRIA - ABIOLA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, September 18, 2018

KO TII TO ASIKO FUN ODO LATI DI AARE ORILEEDE NAIJIRIA - ABIOLA

AYEFELE OKEOWO

Okan lara awon omo Oloogbe Moshood Kasimawo Olawale Abiola, Ogbeni AbdulMumuni Abiola ti so pe kii se iru asiko bayii ni odo lawon fe e de ipo Aare lorileede Naijiria, nitori pe ko tii to asiko.


Ana tii se ojo Abameta, iyen Satide ni AbdulMumuni Abiola fi erongba e han nibi ayeye apapo awon odo, iyen National Youth Summit, akoko iru e ti egbe odo kan nipinle Kwara ti won pe oruko won ni Zealous Kwara Youth niluu Ilorin sagbateru e.

Ninu oro e, o so pe "Mo gbagbo pe asiko kan n bo, gege bo se wa lorileede Canada ati France, ti a maa ni enikan tojo ori e ko tii ju ogbon odun lo nijoba.

"Mi o ro pe asiko naa ti to bayii. Mo lero pe o nidii kan ni pato ti Aare Buhari fi wa nibe, ma a si fe ka ni suuru pelu e. E je ka fun un lanfaani odun merin in min in, ti mo si nigbagbo pe odo ni yoo gbe ijoba fun un.

"Mi o ni eni ti mo tun fe e se ipolongo ibo fun ju eni to wo sunsun leyin ogun odun, to si bu ola fun baba mi, eyi tawon to ku ko se. Idi ni yii, Buhari lemi fe e tele lodun 2019 lati pada leekeji."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI