O Tan O: Ajimobi Ti Ileese Obasanjo Pa N'Ibadan - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, September 18, 2018

O Tan O: Ajimobi Ti Ileese Obasanjo Pa N'Ibadan

IGBAGBOYEMI ESUPOFO

Opo awon ti won gbo nipa igbese ti ijoba ipinle Oyo labe akoso Gomina Abiola Ajimobi loro naa si n ya lenu titi dasiko yiyi nigba ti won gbo pe ijoba ti ileese Aare ana, Oloye Olusegun Obasanjo pa.


Bo tile je pe kii se akoko re e ti Gomina Abiola Ajimobi yoo maa ti awon ileese pa nipinle naa latari esun owo ori ti won je, eyi to fi kan won. Be o ba si gbagbe, lai pe yi nijoba ipinle Oyo naa loo wo ileese gbajumo olorin nni, Yinka Ayefele lule, toro naa si di ariwo, bo tile je pe won ti pada yanju e.

Iroyin to te AWIKONKO lowo je ko ye wa pe ileese Oloye Olusegun Obasanjo, nibi to ti n sin awon nnkan osin to wa lagbegbe Oluyole Industrial Estate, Ibadan ni awon osise ijoba to wa ni eka owo ori, iyen Oyo State Board of Internal Revenue (OYBIR) lo lati loo beere owo ori won, bi won ko se ri lo mu won tii pa.

Lara awon ileese ta a gbo pe won tun ti pa lawon banki, ile epo MRS, Black Horse, Heinemann Educational Books, Lister Flour Mills, University Press Limited, Evans Brother, Brooking House, Group Medical hospital, Butterfield bakery, Chicken Republic ati Rasmed publicity.

Awon ileese naa la gbo pe awon agbegbe bii Dugbe, Eleyele, Podo, Challenge, Onireke niluu Ibadan ni won wa.

Nigba to n soro nipa idi ti won fi ti awon ileese na pa, alaga eka eto ipawo-wole naa, Ogbeni Bicci Alli so pe aimoye igba lawon ti kowe sawon ileese naa pe ki won wa a san owo ori won ti won je, sugbon ti won kan eti-ikun si oro won.

Idi ni yii to lawon fi gbera lati gbe igbese naa, to si n ro awon ileese ti oro naa kan pe ki won tete loo san owo ori won ki asiko too lo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI