LEYIN ODUN META: KASNATY BERE ETO LORI SWEET FM LOJO WESDE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, September 20, 2018

LEYIN ODUN META: KASNATY BERE ETO LORI SWEET FM LOJO WESDE

ABIMBOLA ABERUAGBA

Bi iroyin to te AWIKONKO lowo lai pe yi ba fi le je otito, a je pe adura odun meta ti gbajumo sorosoro nni, Kolawole Adejojo tawon ololufe e tun mo si Kasnaty ti gba bayii.


Ohun ta a gbo ni pe okunrin omo bibi ipinle Osun to filuu Abeokuta sebugbe, eni tawon eeyan n gba tie gidi lasiko yi yoo bere eto agbofikogbon, to tun je akoko iru e lori afefe.

"E MAA FEEL FINE" loruko eto naa, gbogbo Ojoru, Wesde ni eto to pin si abala bii merin naa yoo maa waye laarin ago meta osan si merin irole (3:00pm - 4:00pm), nibi tawon eeyan yoo ti maa mo bo se no lawujo.


'Maa lo moto' la gbo pe yoo je abala akoko lori eto naa nibi tawon eeyan yoo ti maa mo awon isoro to see se ki moto won koju, tawon ojogbon nidi ise mekaniiki yoo ti maa dawon eeyan lekoo nipa moto.

'Ta lo gbo oyinbo ju?' ni won pe abala keji ni tawon to n gbo eto naa yoo ti maa tunmo awon owe Yoruba si ede oyinbo.

Abala 'Ena' ni yoo je abala keta, tawon ololufe e yoo ti gbo nipa ede 'Ena', awon to tun gbo yoo tun fi se efe, bee ni won yoo tun fi pa owe lorisirisi.


Igbadun to se ara oto le o maa je lori eto sorosoro tawon eeyan tun n pe ni 'Aseto bi eni ori e yato' naa nitori pe 'a lo kan, gbe kan ti' ni Kasnaty, kii sii bawon seto to jo ara won.

Fawon to ba mo gbajumo sorosoro naa daadaa, paapaa awon ti kii fi awon eto e lori redio ati telifisan sere, won yoo mo pe ko si asadanu ninu awon eto ti okunrin to feran lati maa je eja tutu naa sere.

Aworan kan ti e n wo nisale yi lo ta AWIKONKO lolobo pe okunrin naa yoo bere eto tawon eeyan ko ni fe e salai ma gbo o lojo Wesde, ti ipalemo si ti n lo lowo.

Bo tile je pe gbogbo akitiyan lati ba gbajumo sorosoro naa soro lati beere idi to fi je ki eto naa pe ko too bere lori redio Sweet, iyen Sweet 107.1FM lo ja si pabo titi ta a fi sakojopo iroyin yi tan. Gbogbo bi a se n pe foonu e ni ko gbe, bee ni ko tii da atejise ori WhatsApp ta a fi ranse si i pada titi ta a fi pari akojopo iroyin yii.


AWIKONKO gbo pe latigba ti won ti bere redio Sweet niluu Abeokuta ni Kasnaty ko ti ba won seto nibe, gbogbo bi won se lawon ololufe e n parowa fun un pe koun naa loo bere lo n so pe ko tii to asiko, sugbon ti asiko naa ti wa a to bayii.

Bo tile je pe a ko tii le fidi e mule daadaa, sugbon lara awon to b'AWIKONKO soro nipa eto tuntun naa so pe ileese redio Sweet lo ranse le okunrin to ko ise labe Oloye Yemi Sonde, iyen Jigan Akala pe ko wa a bere eto nibe, ti won si jo towo bo iwe adehun.

Fun laaye lekunrere, yala lati polowo oja yin, tabi lati ba okunrin naa soro, 08032312479 ni ki e pe e sii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI