MESSI DIBO FUN RONALDO NIBI ETO IDIBO TANI AGBABOOLU TO DARAJU LAGBAYE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, September 26, 2018

MESSI DIBO FUN RONALDO NIBI ETO IDIBO TANI AGBABOOLU TO DARAJU LAGBAYE

...bee ni Gernot Rohr ati Mikel Obi dibo fun Messi

ABIMBOLA ABERUAGBA

Se ni opo awon eeyan la enu won sile, ti won ko le pa a de nigba ti won gbo pe gbajugbaja agbaboolu omo orileede Argentina nni, Lionel Messi dibo fun akegbe e, Cristiano Ronaldo ti orileede Portugal nibi eto idibo lati mo eni to mo boolu gba ju lagbaye.


Iyalenu loro naa je fun opo awon ololufe Messi pelu igbese to gbe yi. Bawon kan se n so pe Messi gba fun oga e ni, bee lawon kan n so pe ko nitunmo, tawon min in si n so pe igbese ti Messi gbe naa ko yato si teni to niteriba ti ko legbe.

Bo tile je pe Messi ko si ninu awon meta ti won mu naa, sibe akonimongba egbe agbaboolu orileede Naijiria, Gernot Rohr ati agbaboolu orileede Naijiria, Mikel Obi dibo fun Lionel Messi ati Modric.

Cristiano Rinaldo, Luka Modric ati Kylian Mbappe lawon meta ti won mu, ti won si n wa eni kan soso ti yoo gba goolu naa.

A gbo pe Rohr dibo fun Modric nipele akoko ati Mbappe nipele keji. Mikel ni ti e dibo fun Messi ti oruko e ko si nibe, bee lo tun dibo fun Mbappe ati Modric.

Ronaldo ni ti e dibo meta otooto fun Raphael Varane, Modric ati Antoine Griezmann.

PÍN-IN KÁÀKIRI