ATUNDI IBO OSUN: EYI NI BI BUHARI SE RAN FAYEMI LOO BE OMISORE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, September 26, 2018

ATUNDI IBO OSUN: EYI NI BI BUHARI SE RAN FAYEMI LOO BE OMISORE

...won ni Omisore nikan lo le gba awon
...Saraki ti loo wa ojurere Omisore tele fun Adeleke

AYEFELE OKEOWO ati IGBAGBOYEMI ESUPOFO

Bi e se n ka iroyin yi, gbogbo lawon adije meji to n lewaju nibi idibo gomina ipinle Osun to n lo lowo yi n wa lati jawe olubori nibi atundi ibo to n bo lojo Tosde ola yii, iyen Seneto Ademola Adeleke ti egbe oselu PDP ati Alaaji Gboyega Oyetola toun wa legbe oselu APC.


Opo awon omo ipinle Osun ti won ri gomina ti won sese dibo yan nipinle Ekiti lai pe yi, Dokita Kayode Fayemi niluu Ile-Ife, ipinle Osun lojo Tusde ana ni won ko siye-meji pe odo Seneto Iyiola Omisore lo n lo pelu oko akoworin e.

Ko si nnkan meji to n gbe Kayode Fayemi, toun ati Aare Muhammadu Buhari jo rin irin ajo lo sibi ipade agbaye kan, United Nations General Assembly kaakiri, bi ko se ona ti atundi ibo to n bo nipinle Osun yoo se mu ki Oyetola jawe olubori, pelu bi won se je omo egbe oselu kan naa.

AWIKONKO gbo pe iroyin kan te Buhari lowo pe eni kan soso to le bawon eeyan soro lati dibo fun Oyetola tegbe oselu APC ni Omisore toun wa legbe oselu SDP, nitori pe oun lo ni Ile-Ife.

Seneto Iyiola Omisore lasiko yi ti di Mesaya (Messiah) tawon oloselu n sa lo ba fun igbala bayii, nitori ti won gba pe nnkan to ba so lawon eeyan yoo gbo.

Ko pe ti won ni Buhari de ibi ipade to lo, niroyin Omisore te e lowo, lesekese lo si ti pase fun Fayemi pe ko pade si Naijiria lati loo wa ona bi yoo ti ba agba oselu to wa lati Ife naa soro, ko le fowosowopo pelu egbe oselu won, APC.

Dokita Fayemi la gbo pe o lo pelu awon igbimo agba egbe oselu APC loo ba Omisore, ti won si joo soro, bo tile je pe won ti fori oro naa ti sibi kan, sugbon ti ko tii seni to le so boya Omisore yoo tewo gba won.

Atundi ibo naa la gbo pe awon ti ko din in ni egberun meta ataabo (3,498) lo ku ti won n reti lati dibo, awon eeyan yi la gbo pe ti Omisore ni won n se, ti ko si seni to le bawon soro ju agba oselu naa lo.

Lojo Monde to koja yii, iyen ijeta ni Seneto Bukola Saraki to je Aare ile igbimo asofin agba orileede yi ti koko sare gba odo adije sipo gomina ipinle naa legbe oselu SDP lo lati loo wa ojurere fun bi yoo ti si awon eeyan ti e lokan lati dibo fun Seneto Adeleke tegbe oselu PDP, ko si le jawe olubori.


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI